Àbẹ̀wò Buhari: Ẹnu kun ìjọba Èkó lori ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́.

Buhari ati Ambode Image copyright @AkinwumiAmbode
Àkọlé àwòrán Ẹnu ti bẹ̀rẹ̀ sí ni kun ìjọba ìpìnlẹ̀ Èkó fún bí ó ṣe kéde ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́.

Àarẹ Muhammadu Buhari ti orílẹ̀èdè Naijiria ti gúnlẹ̀ sí ìpìnlẹ̀ Èkó fún àbẹ̀wò ẹnu iṣẹ́ ọlọ́jọ́ meji.

Lọ́gán tó dé sí ìlú Èkó ló ṣí ibùdókọ̀ tuntun kan tó wà ni Ikẹja, kó tó di pé ó gbéra lọ si ibi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì tó n wáyé fún ayẹyẹ ọjọ ìbí Asiwaju Bọla Tinubu.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Aṣiwaju Bọla Tinubu pé ẹni ọdun mẹ́rìndínlaadọrin.

Ṣùgbọ́n ẹnu ti bẹ̀rẹ̀ sí ni kun ìjọba ìpìnlẹ̀ Èkó fún bí ó ṣe kéde ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, tó sì tún gbé àwọn òpópónà kan tì pa láàrin ìlú nítori àbẹ̀wo Buhari.

Ìgbésẹ̀ nàá mú kí ó nira fún ogúnlọ́gọ́ àwọn èèyàn láti rí ọkọ̀ wọ̀ láti ibìkan sí èkejì.

Àkọlé àwòrán Ará ìlú fi ẹ̀hónú hàn lórí àbẹ̀wò Buhari

Kọmísánnà fún ètò ìròyìn ìpìnlẹ̀ naa, Kẹhinde Balogun, ni àwọn ọ̀nà naa di títìpa "láti le mú ki ètò ààbò f'ẹsẹ̀múlẹ̀ lásìkò àbẹ̀wò ààrẹ".

Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Buhari yóò ṣ'àbẹ̀wò sí ìpìnlẹ̀ Èkó níbi ti àwọn ènìyàn tí ó tó ogún mílíọnù ngbé, láti ọdún 2015 tó ti g'orí àléèfà.