Ìkọlù Zamfara; Ẹ̀nìyàn 60 pàdanù ẹ̀mí nínú ìkọlù darandaran

maapu Zamfara
Àkọlé àwòrán Àarẹ Muhamadu Buhari se àbẹ̀wò sí ágbèègbè náà laipe yii

Àwọn òlùgbè abúlé kan ní ìwọ̀ àríwá ìpínlẹ̀ Zamfara ti sọ fun BBC wípé ọgọ́ta ènìyàn ló pàdánù ẹ̀mí wọn nínù ìkọ̀lù lẹ́ẹ̀mẹ́ta láàárín ọjọ́ méjì láti ọwọ́ àwọn darandaran lágbèègbè náà.

Ilé isẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ náà sọwípé lóòtọ́ ni ìsẹ̀lẹ̀ náà sẹlẹ̀ sùgbọn ènìyàn mẹ́ta làwọn rí òkú rẹ́ nígbà tí àwọn dé ibi ìsẹ̀lẹ̀ náà.

Àwọn méjì tí ọ̀rọ̀ náà sojú rẹ̀ sọwípé agbègbè Bawardaji ni wón ti kọ́kọ́ se àkọlù tí wọ́n sí pa ènìyàn mẹ́tàlá.

Wón sì fikun wípé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ni wón tún pa níbi tí wón ti ń sìnkú àwọn ènìyàn tó káásà ìkọlù alákọ̀kọ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Tí a kò bá gbàgbé, ìsẹ̀lẹ̀ yíí wáyé lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí Àarẹ Muhamadu Buhari se àbẹ̀wò sí ágbèègbè náà, tó sì se ìpàdé pẹ̀lú àwọn ọba àti àwọn àgbààgbà pẹ̀lú àsẹ wípé kí wọ́n palẹ̀ àwọn ọlọ́sà mọ́ lágbèègbè náà.