Ní Kaduna, wọ́n ti sin ọmọógun11 tí àwọn ọ́lọ́ṣà pa

Oku awọn ologun mọ́kànla ti wọn sin l'ọni

Wọ́n tí sin àwọn ologun mọ́kànla tí wọ̀n pa ní ìpínlẹ Kaduna l'ogúnjọ oṣu yíi.

L'Ọ́jọbọ̀ ni wọ́n sin àwọ́n ologun tí wọn pa l'ágbègbé Birnin gwari nipinlẹ Kaduna tó wà l'áriwá Naìjíríà.

Àwọn ọlọ́ṣà ni wọ́n pa àwọn ológun ikọ́ kò-gbéregbé Akpan Apatuma tó ń gb'ógun tí ìkọ́lú àwọn ọ́lọ́ṣà l'agbegbe náà.

Wọ́n pa àwọn ológun ọ̀hún ni lẹyín ìgbà tí wọ́n pa àwọn asáàjú àwọn ọlọ́ṣà kan ní ìpinlẹ́ Zamfara.

Iléesẹ́ ológun Naìjíríà sọ wipe àwọn ológun ọ̀hún ko ní ku lasán.