2019 Election: PDP ní ọgbọ́n àyínìke ní APC lò fún ìdìbò Ọsun, Ekiti

APC

Oríṣun àwòrán, @APC Twitter

Àkọlé àwòrán,

Bola Tinubu ní APC nìkan ni yóò ma sàkóso àwọn ìpínlẹ ní ẹkùn ìwọ̀ Naijiria lẹ́yìn ìdìbò 2019.

Ọkan gboogi lara ẹgbẹ oselu PDP, Diran Ọdẹyemi ti fi ẹsun kan ẹgbẹ oselu APC lorilẹede Naijria wi pe agabagebe lasiko idibo lo jẹ ko dabi ẹni wi pe APC n jẹ gaba ni ẹkun Iwọ-oorun Naijiria.

Ọdẹyemi sọ eyi fun BBC Yoruba gẹgẹ bi o ṣe bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti Alaga ẹgbẹ oselu APC, Bola Tinubu sọ wi pe APC yoo di ti ẹgbẹ oselu APC lẹyin idibo 2019.

O ni kii se ti ẹgbẹ oselu APC lati sọ wi pe ilẹ Yoruba ma a di ti APC ati wi pe ahesọ lasan ni.

Àkọlé fídíò,

Abdulfatah Ahmed: PDP kò fi tíkẹ́ẹ̀tì mi fa ojú ẹnìkejì mọ́ra

Ninu ọrọ rẹ, Ọdeyemi ni awọn to jẹ agba ni ilẹ Yoruba ati awọn ẹgbẹ ọmọ ilẹ Oodua, Afẹnifẹrẹ ati Yoruba Patriotic Movement ko fi pamọ wi pe ẹgbẹ oselu PDP ni awọn n se atilẹyin fun.

Ọkan gboogi lẹgbẹ oselu PDP naa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun si n gbọ ẹjọ eto idibo ipinlẹ Ọsun ati Ekiti, nitorina APC ko lasẹ lati sọ wi pe awọn lo ni isakoso awọn ipinlẹ gbogbo to wa ni ilẹ Yoruba.

'Òtítọ́ ni Tinubu sọ, APC ti gba ilẹ̀ Yorùbá'

Oludije si ipo gomina ni ẹgbẹ oselu ADC ni ipinlẹ Ọyọ ti sọ wi pe otitọ ni ọrọ Bola Ahmed Tinubu wi pe o seese ki ẹgbẹ oselu APC o gba gbogbo ilẹ Yoruba.

Yinus Akintunde sọ pe nibayii ẹgbẹ oselu APC ti gba ipinlẹ Ekiti, Ondo, Ọyọ, Eko, Ogun ati Ọsun ti ko si si ẹgbẹ alatako kankan ni ilẹ Yoruba.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Bola Tinubu ní APC nìkan ni yóò ma sàkóso àwọn ìpínlẹ ní ẹkùn ìwọ̀ Naijiria lẹ́yìn ìdìbò 2019.

O fikun wi pe o ti sẹlẹ ni ọdun 1999 ti o jẹ wi pe ipinlẹ marun si mẹfa wa labẹ isakoso ẹgbẹ oselu kan ti ohun gbogbo si n lọ deede.

Àkọlé fídíò,

Onigbajamọ: Báwo lẹ se gbọ́ èdè Yorùbá sí?

Amọ ninu ọrọ rẹ, ipa ti awọn oloselu ti awọn ara ilu ba yan si ipo ba mu ileri wọn sẹ lẹyin idibo 2019, ẹgbẹ kan ni ilẹ Yoruba yoo ma se.

Oludije labẹ ẹgbẹ oselu ADC naa wa fikun pe afojusun ati imusẹ ileri ni Ila-Oorun, Iwọ-Oorun, Ariwa ati Guusu orilẹede Naijiria le jẹ ko seese ki ẹgbẹ oselu kan jẹ gaba nipa isakoso orilẹede Naijiria.

Kò sí àyè fún ẹgbẹ́ òsèlú míì nílẹ̀ Yorùbá - Tinubu

Adari apapọ fẹgbẹ oṣelu APC, Oloye Ahmed Bola Tinubu ti fọrọ lede wipe ẹgbẹ oṣelu APC nikan ni yoo maa ṣe akoso gbogbo ipinlẹ to n bẹ ni ẹkun iwọ-orun orilẹede Naijiria lẹhin idibo ọdun 2019.Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri ọhun sọ ọrọ naa di mimọ nibi ayẹyẹ iburawọle fun gomina tuntun nipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla, to waye ni papa iṣere ilu Ọṣogbo lọjọ Iṣẹgun.

Àkọlé àwòrán,

Tinubu ní Oṣun

O ni ko si anfani kankan ti orilẹede Naijiria jẹ ninu gbogbo odun mẹrindinlogun ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo lorii apere ijọba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Jide Kosọkọ: Isẹ́ tíátà yóò gòkè tíjọba bá gbówó kalẹ̀ láti seré

Tinubu fi kun ọrọ rẹ wi pe aifi ipilẹ rere lelẹ lati ọwọ ijọba ti o ti ṣe tẹlẹri lo mu ki aarẹ Buhari maa damu ninu igbiyanju rẹ lati tun orilẹede yii ṣe.O tẹsiwaju wipe ko si anfani fun ẹgbẹ oṣelu mii lati ṣe akoso Naijiria ati awọn ipinlẹ ẹkun iwọorun nitori wipe ẹgbẹ APC ko tii yori iṣẹ rere to bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Bola Tinubu ní APC nìkan ni yóò ma sàkóso àwọn ìpínlẹ ní ẹkùn ìwọ̀ Naijiria lẹ́yìn ìdìbò 2019.

O parọwa si gomina tuntun nipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla lati ṣe awokọṣe awọn iṣẹ rere ti gomina tẹlẹri, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ṣe nipinlẹ Ọṣun.

Ẹ má dáríji PDP — Tinubu

Asaáju ninú ẹgbẹ́ òṣèlú APC to ń ṣe ìjọba ní Naìjíríà, Bola Ahmed Tinubu, ti ké sí àwọn ọmọ Naìjíríà pe kí wọ́n má gbá ìtoro àfóríjì tí ẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP tọrọ l'ọ́wọ wọn fún àṣìṣé ti wọn ṣe fún ọdún mẹ́rìdinlogún.

Tinubu pe ìpè yí lasìkó ayeye ọdún kèrìndínláàdọ́rìín rẹ̀ tó waye nilú Èkó.

Àkọlé àwòrán,

Asaáju APC ọ̀un ni PDP lu owo ìjọba ni ponpo nitorí náà kí àwọn ọmọ Naìjíríà má gba wọn laye mọ

Nígba to n sọ̀rọ̀ laarin awọ̀n eekàn tó pé sibi ayeye ọjọ́ ìbi rẹ̀, Tinubu sọ wi pe ona àti tan àwọn ọmọ Naìjíríà jẹ ni èbè ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ń bẹ̀.

Asaáju APC ọ̀un sọ pé ẹgbẹ náà lu owo ìjọba ni ponpo nitorí náà kí àwọn ọmọ Naìjíríà má gba wọn laye mọ.