Àwọn ilé iṣẹ́ àbò lorílẹ̀ẹ̀dé Naìjíríà ń foyà lori ìbo 2019

Aarẹ Buahari ati awọn ọgaagba ologun duro ninu asọ ogun Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lai pe yi ni Ileesẹ ologun koro oju si atejade kan ti Amnesty International gbe jade lori wọn

Awọn ọga ileesẹ abo Naijiria ni ominu n kọ wọn lori bi awọn kan ti ṣe ń gbero lati gbegidina eto idibo 2019.

Agbẹnuso Aarẹ orilẹẹde Naijiria Garba Shehu lo lede ọrọ na ninu atẹjade kan.

Sheu ni awọn olori eka naa ke gbajare nigba ti wọn jomitoro ọrọ pẹlu awọn akoroyin nile ijọba l'Abuja.

O ni wọn sọ pe ''ero'ngba awọn egbe ti ko loruko naa ni ki won da gbonmisi-omi-o-to sile l'agbo oṣelu.''

Lara awọn ti wọn ba awọn akoroyin sọrọ ni oludari agba fun ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ ni Naijiria, DSS, Lawal Daura, oludari ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ nilu okere, NIA, Ahmed Abubakar ati Ọgagun agba patapata lorilẹede Naijiria, Ọgagun Abayọmi Ọlọnisakin.

Garba Shehu ni awọn asiwaju ikọ alaabo naa pe fun ifọwọsowọpọ awọn akoroyin lati koju awọn ẹgbẹ agbesunmọmi ilu okere ti yoo fẹ bẹnu atẹ lu akitiyan ijọba lati mu abo to peye ba awọn ara ilu.