Umar Buba Jibril kú lẹ́ni ọdún 58

Aworan Umar Buba Jibril Image copyright Twitter/House of Reps NGR
Àkọlé àwòrán Wọ́n sàpèjúwe olóògbé náà gẹ́gẹ́ bíi olóòtọ̀ àti akíkanjú asòfin

Agbẹnusọ fún Ilé Ìgbìmọ̀ Asojúsòfin lórílẹ̀èdè Nàìjírìà, Yakubu Dogara ti kéde ikú Igbákejì Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin, Umar Buba Jibril lẹ́ni ọdún méjìdínlọ́gọ́ta (58) .

Jibril tó ń sojú ẹkùn ìdìbò Lọkọja n'ìpínlẹ̀ Kogi, papòdà lọ́gbọ̀njọ́, Osù Kẹta, 2018 ní ìlú Abuja tó jẹ́ olú ilú órílẹ̀èdè Nàìjírìà.

Dogara nínú àtẹ̀jáde kan tó sọwípé olóyè Buba náà papòdà léyìn àìsàn ọlọ́jọ́ gbọọrọ, sàpèjúwe olóògbé náà gẹ́gẹ́ bíi olóòtọ̀ àti akíkanjú asòfin.

Àwọn iròyin ti ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lórí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀, Twitter, àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin dárò, wọ́n sì gbàdúrà fún mọ̀lẹ́bíí rẹ̀ pé kí Ọlọ́run ó dúró tì wọ́n lásìkò yíí.