Koko iroyin: APC, PDP lori oruko asebaje, Ipapoda Asofin

Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.

PDP fèsì sí orúkọ àwọn asèbàjẹ́ ti APC gbe jade

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Alaga ẹgbẹ Oselu PDP, Uche Secondus, Alukoro ẹgbẹ Oselu PDP tẹlẹri, Olisa Metuh wa lara oruko awon asebajẹ

Ẹgbẹ́ òsèlú PDP lòrílẹ́èdè Nàíjiríà ti bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn orúkọ ti ìjọba orilẹede Naijiria gbe jade gẹ́gẹ́ bi awọn to lu owo ilu ni ponpo labẹ ijọba PDP fun ọdun mẹrinlelogun.

Minisita fọrọ Iroyin, Lai Muhammed to fi orukọ awọn asebajẹ naa lede ninu atejade fun awọn oniroyin sọrọ ni ilu Eko, sọwipe awọn to lu owo ilu ni ponpo naa jẹ gbajugbaja ninu ẹgbẹ oselu PDP.

Igbákèjì Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin papòdà lẹ̀ni ọdún 58

Jibril tó ń sojú ẹkùn ìdìbò Lokoja ati Kogi ní ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi, papòdà lọ́jọ́ Ọgbọ̀n, Osù Keta ọdún yii, ní Abuja tó jẹ́ olú ilú órílẹ̀èdè Nàìjírìà.

Dogara nínú àtẹ̀jáde kan tó sọwípé olóyè Buba náà papòdà léyìn àìsàn ọlọ́jọ́ gbọọrọ, sàpèjúwe olóògbé náà gẹ́gẹ́ bíi ẹni olóòtọ̀ àti akíkanjú asòfin. Ẹ ka ẹkunrẹrẹ rẹ ni bii

Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni

Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC

Fidio wa fun toni

Àdúgbo mélo lọ́ mọ̀ l'Ábeòkutá?

Àkọlé fídíò,

Óríṣiríṣi ní orukó àdúgbo l'Ábeòkutá