Wọn ti tún kọlu Maiduguri

Aaye kan ti wọn kọlu ni Maiduguri Image copyright Getty Images

Awọn afurasí kan ti kọlu àdugbó Muna Garaj to wa nigboró Maiduguri nipinlẹ Borno, ni irọlẹ́ ọjọ́ Ẹtì.

Ìroyìn sọ wipe botilẹ̀ je pé àwọn afurasi náà nìkán ni wọn ku ninú ikọlu náà, àwọn éèyàn míran farapa.

Kò si ẹgbẹ kan to sọ pé oun ló ṣe iṣẹ́ náà, sùgbọn àwọn óǹwoyé kan rò wipe iṣẹ́ ọwọ Boko Hara ni.

Alaga àjọ tó ń ṣe ìranwọ pàjawìrì ni ìpinlẹ Borno tẹlẹ̀ ri to jẹ alaga àjọ tó ń ṣe ìrànwọ nipinlẹ náà, Satomi Ahmad sọ fún akọroyín BBC pe ìkọlù náà pin si mẹta ọ̀tọ̀ọ̀.

O ṣalàye pe ìkọlù náà ṣẹlẹ̀ ni nǹkan bíi áàgo mẹ́san ààbọ̀ alẹ́ ọjọ Ẹtì.