Ilé wo pà 'yàn meji l'Èkó

Wọn fẹ wo ile naa ni tẹlẹ

Oríṣun àwòrán, Agege TV

Ile kan ti da wo pa awọn eeyan meji l'agbegbe Agege ni ipinlẹ Eko.

Atejade kan ti agbẹnusọ fun ajọ to n ṣe iranwọ pajawiri nipinlẹ Eko, Kehinde Adebayọ, gbe jade sọ wipe wọn yọ ẹnikẹta, Mustapher Salaudeen, laaye ninu ile to dawo naa.

Ajọ naa sọ wipe awọn ti ile naa wo pa ni Toyin Ogundimu, ẹni ọdun marundinlogoji, ati Sherifat Olalere, ọmọ ọdun mọkanla.

Ile ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ wa ni opoponaa Abeje ni Markaz to wa l'Agege.

Oríṣun àwòrán, Agege TV

Ileeṣẹ to n ṣe iranwọ pajawiri ni ipinlẹ Eko wa ninu awọn ti wọn lọ ran awọn ti iṣẹlẹ naa kan l'ọwọ.