Alága PDP fẹ́ gbé Lai Mohammed lọ ilé ẹjọ́

Uche Secondus

Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Uche Secondus, ti fun minisita fun iroyin ati aṣa Naijiria, Lai Muhammaed ni ọjọ meji ko fi yọ oruko ọhun kuro ninu oruko awọn to kede pe wọn ṣe owo Naijiria baṣubaṣu, tabi ko foju ba ile ẹjọ.

Minisita naa ti kọkọ fi ẹsun kan alaga ẹgbẹ alatako naa pe o gba igba miliọnu naira l'ọwọ onimọran aarẹ lori aabo l'ọdun 2015.

Àkọlé fídíò,

Ko sọna ni APC ati PDP

Sugbọn ninu iwe kan ti agbẹjọro Secondus kọ si Lai Mohammed, o ni ki minisita naa da ọrọ naa pada, ko tọrọ aforiji ko si tun san biliọnu kan aabọ gẹgẹ bi itaran.

Agbejọro fun Secondus sọ wipe orukọ rẹ ti Lai Mohammed da ninu awọn to ṣe owo ilu baṣubaṣu ti ba alaga PDP naa lorukọ jẹ.

Bakan naa, alukoro fun ẹgbẹ alatako PDP tẹlẹ ri, Olisa Metu, sọ pe igbese ti minisita naa gbe yoo ko awọn adajọ ni papamora lati ri pe oun jẹbi ẹsun ti ijọba fi kan.