Buhari takó Ambọ̀de lori ńǹkan to gbé e lọ s'Èkó

Ambode ati Buhari

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe ohun ko lọ si ipinlẹ Eko lati ṣii igboro 'Eko Atlantic' to wa leti okun.

Lori ikanni opo Twitter rẹ̀, Aarẹ Buhari sọ pe oun kan bẹ 'Eko Atlantic City' wo ni, dipo lilọ sibẹ lati ṣii.

Skip Twitter post, 1

End of Twitter post, 1

Aarẹ Buhari sọ eleyi lẹyin igba ti gomina ipinlẹ Eko, Akinwumi Ambọde, sọ pe Aarẹ Buhari lọ ṣi 'Eko Atlantic City' lori ikanni opo Twitter rẹ. Sugbọn oti yọ ọrọ naa kuro nibẹ.

Lati ọdun 2013 ni, Aarẹ tẹlẹri, Goodluck Jonathan, ati Aarẹ Amerika tẹlẹri, Bill Clinton ati gomina ipinlẹ Eko nigba naa, Babatunde Raji Fashola ti ṣii igboro 'Eko Atlantic City' ọhun.