Alákatákitì Mali yóò f'ojú winá òfin nilé ẹjọ́ àgbàye

Ololgun aabo ajọ isọkan agbaye kan lati orilẹede Burkina Faso duro ni waju mọṣalaṣi Djinguereber to to ẹgbẹ̀ta (600) ọdun ni Timbuktu, Mali Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn alakatakiti Islam wo iboji oku to wa ni mọṣalaṣi Djingareyber ni Timbuktu l'ọdun 2012

Ọwọ́ ilé ẹjọ́ àgbayé to wà ni Hague ti tẹ afurasi kan ti wọn ń wa lori ẹsun ìrufin ogun ni Mali, lẹyín ìgbà ti àwọn alaṣé nawọ́ rẹ̀ si ilé ẹjọ́ náà.

Al Hassan Ag Abdoul Aziz Ag Mohamed Ag Mahmoud lo lewajú àwọn ẹ̀ṣọ́ alákátákitì ọ̀hun ni Timbuktu nigba ti ilu náà fi wa l'abẹ́ wọn.

Wọn fi ẹ̀sùn kan wipe o n ko tẹ ẹ̀tọ àwọn obirin ati ọmọbirín mọ lẹ pẹ̀lu kikowọn ni papámorá lori ki wọn fẹ àwọn alákatákití Islam.

Wọn tún fi ẹ̀sun kan wipe o gbiyanju lati ba iboji àtijọ́ jẹ́ ni Timbuktu.

Related Topics