Arsenal na Stoke City pẹ̀lu àmì ayò mẹtá s'odo

Oríṣun àwòrán, Reuters
Pierre-Emerrik Aubameyang lo bá Arsenal gba bọ́ọ̀lu meji wọle ninu ifẹsẹ̀wọsẹ̀ náà
Ikọ́ agbabọ́ọ̀lú Arsenal ti f'àgbà han Stoke City lẹyín ìgbà ti wọn gba bọ́ọ̀lu mẹta ọ̀tọ̀tọ̀ s'awọn wọn ninú ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dogún ìkayìn ìfẹsẹ̀wọ̀nsẹ̀ wọn l'ọjọ́ Àiku (Sunday).
Pierre-Emerick Aubameyang lo kọ́kọ́ bá Arsenal jẹ bọ́ọ̀lu ni ìṣẹ́jú káàrùndinlọ́gọ́rin si ìgbà ti wọn bẹ̀rẹ ere náà pẹ̀lú ayo gbée-lẹ̀-kó-gbá-sílé (penalty).
Aubmaeyang náà lo tún jẹ bọ́ọ̀lu nigbà ti wọn ti gbá ere bọ́ọ̀lu ọ̀hun to ìṣẹ́jú mẹ́rindinlàádọrùún.
Sugbọn nigba ti ere di ìṣẹ́jú mọ́kandinlàádọ́rùún Alexander Lacazette lo ba ẹgbẹ gbabọ́ọ̀lu Arsenal gba bọ́ọ̀lu sinu àwọn pẹ̀lú ayo gbée-lẹ̀-kó-gbá-sílé (penalty).
Lẹyín ìfẹsẹ̀wọ̀nsẹ̀ náà, akọ́nimọ́ọ̀gbá Arsenal, Arsen Wenger, gb'oriyìn fun ẹgbẹ́ agbabọ́ọ̀lú Stoke City pẹ̀lú bi wọn ṣe jà fitáfitá.