Dele Alli ba Tottenham na Chelsea mọ'le

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbe agbabọ́ọ̀lu Tottenham ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rinlẹ̀ lori àtẹ ìgbelewọn liígi ilẹ Gẹ́ẹ̀sì lẹyin ìgbà ti wọn na Chelsea mọ'le pẹ̀lú àmì ayò mẹta s'ẹyọ̀kan.
Alvaro Morata lo kọ́kọ́ gba bọ́ọ̀lu sinu àwọn Tottenham fun Chelsea ni ọgbọ̀n ìṣẹ́jú si ìgbà ti wọn bẹrẹ ìfẹ́sẹ̀wọnsẹ̀ náà.
Christian Eriksen lo ba Tottenham jẹ bọ́ọ̀lu lasiko ti wọn fẹ lọ fún ìsimi ìdajì àsìkò.
Sùgbọn Dele Alli lo ba Tottenham ṣẹgun nibi ìfẹ́sẹ̀wọnsẹ̀ náà nigba to jẹ bọ́ọ̀lu meji lẹyin ìṣẹ́jú mejìlelọgọtá (62) àti mẹrìndinlàádọrin (66) si igba ti wọn bẹrẹ ìfẹ́sẹ̀wọnsẹ̀ náà.
Oríṣun àwòrán, Reuters