Ìjọba Nàìjíríà tún ti gbe orúkó àwọn 'tan kowojẹ' jade

Lai Mohammed

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìjọba Nàìjíríà tún ti gbe orúkó àwọn ti o furasi pe wọn ko owo orilẹede naa jẹ jade.

Ijọba apapọ ṣe alaye wipe akọsile orukọ awọn to ko owo orilẹede yi lọna aitọ kii ṣe arosọ, gẹgẹ bo ti ṣe afihan isori keji akọsilẹ awọn eeyan to kowo orilẹede yi lọna aitọ.

Lasiko ti o n kede isọri keji akosilẹ naa ninu ọrọ ti wọn fi lede loni ni ilu Eko, alakoso fun iroyin ati aṣa, Alhaji Lai Mohammed, ṣe alaye wipe ohun ti ko ye awọn eeyan ton fi apa janu lori awọn orukọ ti wọn fi lede saaju ni wipe ijọba sẹẹsẹ n mu ẹyẹ bọ lapo ni.

Mohammed juko ọrọ si ẹgbẹ oselu PDP lori bi o ṣe pe ijọba apapọ nija lori ẹsun ti ẹgbẹ na jebi si.

Minisita naa tẹsiwaju wipe igbese ẹgbẹ oṣelu PDP lori awọn orukọ ti ijọba apapo kede lo n ṣe afihan rẹ wipe ọgbọn ẹwẹ ni aforiji ti ẹgbẹ oṣelu naa n tọrọ lọwọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

ISỌRI KEJI AWỌN ORUKỌ TIJỌBA FI LEDE

1. Alamọran fu eto aabo tẹlẹri, Sambo Dasuki

2. Minisita fun alumọni epo rọbi tẹlẹri, Dieziani Alison-Madukwe

3. Ajagun fẹyinti Kenneth Minimah

4. Ọgagun Azubuike Ihejirika

5. Alakoso tẹlẹri fun eto aabo, Alex Barde

6.Alakoso ẹsọ asọbode tẹlẹri, Inde Dikko

7. Asoju awọn ọmọ ogun oju ofurufu, Adesola Amosun

8. Alakoso olu-ilu ilẹ wa tẹlẹri, Sinatọ Bala Abdulkadir

9. Sinatọ Stella Oduah

10. Gomina ipinlẹ Niger tẹlẹri, Babangida Aliyu

11. Gomina ipinlẹ Plateau tẹlẹri, Sinatọ Jonah Jang

12. Alakoso fun eto ẹnawo tẹlẹri, Bashir Yuguda

13. Sinatọ Peter Nwaboshi

14. Alabasisẹ pọ Dasuki tẹlẹri, Aliyu Usman

15. Amugballgbẹ Dasuki tẹlẹri, Ahmad Idris

16. Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹri, Rasheed Ladoja

17. Tom Ikimi

18. Femi Fani-Kayode

19. Alabasisẹpọ aarẹ Goodluck tẹlẹri, Hassan Tukur

20. Nenadi Usman

21. Benedicta Iroha

22. Alabasisẹ pọ Dasuki tẹlẹri, Aliyu Usman Jawaz

23. Godknows Igali