PDP: Bí Mantu bá yí ìbò, ara rẹ̀ ló yíi fún

Sẹ́nétọ̀ Ibrahim Mantu

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig

Àkọlé àwòrán,

Tani Mantu yí ìbò fún?

Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP lórílẹ̀èdè Nàíjíríà ti sọ wí pé, kò sí ìgbà kan tí ààrẹ ilé aṣòfin àgbà nígbàkanrí, Sẹ́nétọ̀ Ibrahim Mantu ṣètò màgòmágó ìbò fún ẹgbẹ́ òṣèlú náà gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ láìpẹ́ yìí.

Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta ni ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti sọ èyì di mímọ̀.

Ó ní lóòótọ́, Sẹ́nétọ̀ Ibrahim Mantu leè ní àwọn ìwà ìbàjẹ́ tí òun fùnrarẹ̀ gùnlé láìsí ẹni tó rán an, ṣùgbọ́n ó dájú pé kò ṣe ìwa ìbàjẹ́ náà fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Kola Ologbodiyan: Jẹgudu jẹra ni ijọba APC

Àkọlé fídíò,

Ko sọna ni APC ati PDP

"Kò sí ibi kan tí a kọ ọ́ sí pé, kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí olùdíje nínú ẹ́gbẹ́ òṣèlú yìí, ṣe màkàrúrú ìbò fún ẹgbẹ́ òṣèlú náà."

Kín ló dé tí Màǹtú kò se yí ìbò fún ara rẹ̀?

Láìpẹ́ yìí ni Sẹ́nétọ̀ Ibrahim Mantu ṣàlàyé lórí ètò iléeṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ kan pé, òun ṣe màgòmágó ìbò gẹ́gẹ́ bi olóṣèlú, eléèyí tó ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye.

Àtẹ̀jáde náà ní, "ṣèbí Sẹ́nétọ̀ Ibrahim Mantu pàdánu ìbò sípó sẹ́nétọ̀ lọ́dún 2007, kò ṣe lo ètò màgòmágó rẹ̀ nígbà náà."