Iná Oǹdó: Oṣìsẹ́ iléeṣẹ́ amúnáwá BEDC gan mọ́'ná

Òpó iná ọba kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Gbogbo ìgbésẹ̀ pípe àwọn tó yẹ kí Shana pè kí ó tó gun orí òpó yìí ni ìròyìn sọ wí pé ó gbé

Òṣìsẹ́ iléeṣẹ́ amúnáwá BEDC kan ló ti fara kááṣá iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì ní ìlú Oǹdó ní ìpínlẹ̀ Oǹdó.

Ẹ̀ka iléeṣẹ́ amúnáwá BEDC tó wà ní ìlú Oǹdó ni arákùnrin náà, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Adenodi Shana, ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi onímọ̀ ẹ̀rọ kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó sẹ̀ ní ọjọ́ àìkú.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ti fa ìbànújẹ́ ọkàn èyí tó ti pa iná àjọyọ̀ ọdún àjíǹde lágbègbè náà báyìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Tóyìn Adégbọlá: Kò yẹ kí obìnrin fi ìdí gba ipò tíátà

Gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn agbègbé náà ti ṣe sọ, ń ṣe ni arákùnrin náà lọ yanjú wàhálà kan tó wáyé lórí òpó iná kan ní òpópónà Tẹ́wọ́gboyè ní agbègbé New town kí iná ọba tó gbé e.

Ìsẹ̀lẹ̀ náà pa àjọ̀dún àjíǹde lára

Ìròyìn sọ wí pé ọ̀gbẹ́ni Shana ti gbé ìgbésẹ̀ pípe gbogbo àwọn tó yẹ kó pè kí ó tó gun orí òpó yìí, ṣùgbọ́n ohun tó fàá tí iná fi dé bá a lórí òpó ni kò tíì yé ẹnìkan.

Níbáyìí, àwọn ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwáàdí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ni a gbọ́ wí pé òṣìsẹ́ iléeṣẹ́ amúnáwá BEDC máàrún ni wọ́n ti pè fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lóríi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.