Ethiopia: Abiy Ahmed ni olóòtú ìjọba tuntun

Abiy Ahmed

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Abiy ni olotu ijọba akọkọ ọmọ ẹya Oromo lati ọdun mẹtadinlọgbọn ti EPRDF ti wa ni ijọba.

Wọn ti bura sipo fun Abiy Ahmed gẹgẹ bi olóòtú ìjọba orilẹẹde Ethiopia.

Ahmed ni yoo rọpo Hailemariam Desalegn, to kọwe fipo silẹ losu to kọja.

Ibura sipo rẹ la gbọ wi pe o n waye ni ile igbimọ asofin nibi ti yoo ti ba awọn asofin sọrọ.

Ko ti daju boya yoo salaye ojupọnna ti ijọba re yoo tọ nibi ayẹyẹ naa.