Fani Kayode: Bùhárí ló lẹ̀bi Emir tí Olúwòó ń pe ara rẹ̀

Aworan Femi Fani kayode ati Oluwo

Oríṣun àwòrán, FFK/OLUWO

Àkọlé àwòrán,

Ẹnu kìí sin lara Femi Fani Kayode ati Oluwo

Ẹni ba se ohun tẹnikan ko se ri, o di dandan ko gbọ ariwisi ti enikan o gbọ ri.

Igbesẹ Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi, lo fa sababi ọrọ yi.

Ọba alade naa lopin ọsẹ we lawani fun Waziri gbogbo ilẹ Yoruba.

Bakanna lo fi ara rẹ jẹ Emir akọkọ fun ilẹ Yoruba.

Ọpọ eeyan lo ti fesi si igbesẹ ọba alade naa pẹlu bo se yan oye Emir laayo, ti oju opo ikansira ẹni si kun fun ifapa janu awọn eniyan lori ọrọ yii.

Fẹmi Fani-Kayode, tii se Minista fun eto irinna oju ofurufu nigbakan ri lorilẹede Naijiria naa dasi ọ̀rọ̀ yii.

Fẹmi Fani-Kayode ni, aarẹ Buhari lo ni ẹbi bi oluwoo se npe ara rẹ ni Emir.

Ninu ọrọ re to kọ loju opo Twitter rẹ, Fani-kayode ni sugbọni kii se Buhari nikan lo lẹbi ọrọ naa.

Bakanaa ni agbarijọpọ ẹgbẹ ọdọ nilẹ Yoruba ti sọrọ kobakungbe si Ọba Adewale Akanbi lorii bo se tẹwọgba oye Emir, to si pa oye Oluwo ti.

Egbẹ ọdọ Yoruba naa fọnmu lori ihuwasi Oluwoo

Alakoso ẹ́gbẹ́ YYSA, Ọlalekan Hammed ni, ti wọn ko ba tete wa nkan se lori ọrọ yii, o seese ko di wahala nla lọjọ iwaju.

"Ko seese fun Oluwoo lati di Emir nitori ipo Oluwoo kii se ti Musulumi , oye adayeba ni.

"Ko si dara ki awọn asaaju nilẹ Yoruba, ti a ko asa le lọwọ, maa ba asa jẹ, eyi ko bojumu to."