China: A fẹ́ dí àdánú òfin owó orí ọjà tí Amẹ́ríkà se

Ọtí wáìnì
Àkọlé àwòrán,

Ọtí wáìnì náà wà lára èròjà tí orílẹ̀èdè China ń lò láti gbẹ̀san àfikún owó orí ọjà

Orílẹ̀èdè China ti kéde àfikún owó orí ọjà tótó ìdá mẹ́ẹ̀dọ́ọ́gbọ̀n nínú ìdá ọgọ́rùn ún lórí àwọn ọjà tó ń wá láti Amẹ́ríkà,

Méjìdínláàádóje lawọn oja naa tó fi mọ́ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti ọtí wáínì.

Ìgbèsẹ̀ náà wáyé lẹ́yìn ti Ààrẹ Donald Trump mú àgbéga bá owó orí irin tútù àti alumílíọ̀nù tó ń wá láti ilẹ̀ òkèèrè ní osù tó kọjá.

Ọjọ́ ajé ní ìgbèsẹ̀ náà, tó ń se àkóbá fún ọjà tówó rẹ̀ tó bílíọ́ọ́nù mẹ́ta dọ́là bẹ̀rẹ̀.

China ní awọn gbe ìgbésẹ̀ náà láti dáábò bo orílẹ̀èdè àwọn, kó sì tún dí òfò táwọn ri láti ipasẹ̀ àfikún owó orí ọjà ti Amẹríkà se.

Gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀èdè Amẹríkà ti sàlàyé, àfikún owó orí ọjà náà wáyé láti tako bí orílẹ̀èdè China se ń figagbága pẹ̀lú ọrọ̀ ajé ilẹ̀ náà lọ́nà tí kò tọ́.

Sùgbọ́n kò sí ẹni tó leè sọ bóyá orílẹ̀èdè China yóò gbé ìgbésẹ̀ tó gbópọn láti máa fi ta tẹ́tẹ́ tako orílẹ̀èdè Amẹríkà

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: