Winnie Mandela di olóògbé lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin

Àkọlé fídíò,

Ìtàn ìgbésí ayé Winnie Madikizela-Mandela

Winnie Mandela, aya nígbà kan rí fún ààrẹ alawọ̀ dúdú àkọ́kọ́ ní orílẹ̀èdè South Africa ti papòdà lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin.

Bí o tilẹ̀ jẹ́ wípé òun àti ọkọ rẹ̀ ti pínyà, kó tó di wípé wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀ ní 1996, Winnie Madikizela Mandela, bí gbogbo ènìyàn ṣe mọ̀ ọ́, jẹ́ gbajú-gbajà nínú ìgbéayé Nelson Mandela.

Winnie Mandela ṣi wà ní ọlọ́mọge nígbà tó di gbajúmọ̀ l'ágbo òṣèlú. Ìjáfáfá rẹ̀ farahàn lásìkò tí ó di òpó òṣèlú tí ọkọ rẹ̀ gbékalẹ̀ mú nígbà tí wọ́n jù ú sí ẹ̀wọ̀n gbére ní 1964.

Àkọlé àwòrán,

Winnie wa pẹ̀lu Mandela nigbati o kuro ni ewọn Victor Verster ọdun 1990 in Paarl

Wọ́n le kúrò ní ìlú lọ si Brandford ní nkan bí ọdún 1970 fún ipa tó kó nínú ìfẹ̀hónúhaǹ tí wọ́n n pè ní ''Soweto Uprising".

Bí ọkọ rẹ̀, Winnie nàá lo ìgbà l'ọ́gbà ẹ̀wọ́n, nítorí pé ó n ṣ'òṣèlú.

Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wípé wọ́n ri bi ohùn fún àwọn aláwọ̀ dúdú tó jẹ́ akúṣẹ̀ẹ́, bí ọdún ṣe n yí lura wọn, ni iyì rẹ̀ n dínkù nítorí àwọn àríwísí kan.

Ara ohun tó ba iyì rẹ̀ jẹ́ ni - bí o ṣe fi ọwọ́ sí sí so àjókù táyà mọ́ ẹni tó bá lùgbàdì ibi. Bákanna ni ìhùwàsí àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò rẹ̀ tí wọ̀n n pè ni "Mandela United Football Club.''

Wọ́n fi ẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n lọ́wọ́ nínúu ìjínigbé àti ìṣekúpa Stompie Moeketsi, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá.

Àkọlé àwòrán,

Nelson àti Winnie Mandela nígbà tí wọ́n da sílẹ̀ l'ọ́gbà ẹ̀wọ̀n l'óṣù Kejì ọdún 1990

Lóòtọ́ ni abílékọ Mandela kò ṣ'ẹ̀wọ̀n fún ipa tó kó, ìgbìmọ̀ olùwádìí tí Àlùfá Desmond Tutu léwájú, ''Truth and Reconciliation Commission" fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó kó ipa pàtàkì nínú ìṣẹ̀lẹ̀ naa.

Ṣùgbọ́n l'áwọn ọdún tó gbẹ̀yìn ayé rẹ̀, abilekọ Mandela dúró bí i àmì àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn - óun ránni létí àwọn akọni ọkùnrin àti obìnrin tó mú òpin dé bá ìṣèjọba àwọn aláwọ̀ funfun.

Ẹ̀wẹ̀, ó jẹ́ ọ́kan lára àwọn díẹ̀ tó bu ẹnu àtẹ́ lu kìkọlù àwọn àjèjì ní South Africa lásìkò ìṣèjọba ààrẹ Thabo Mbeki.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: