Winnie Mandela d'olóògbé lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin

Winnie Mandela
Àkọlé àwòrán,

Aya ìgbàkan rí fún ààrẹ orílẹ̀èdè South Africa tẹ́lẹ̀rí, Nelson Mandela

Winnie Mandela, aya ìgbàkan rí fún ààrẹ orílẹ̀èdè South Africa tẹ́lẹ̀rí ti jẹ́ ọlọ́run nípè lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin, gẹ́gẹ́bí olùránlọ́wọ́ rẹ̀ ṣe sọ.

Winnie Madikizela Mandela ni iyawo akọkọ ti aarẹ adulawọ akọkọ ni orilẹede South Africa, Nelson Mandela.

Awọn tọkọtaya mejeeji jọ gbogun ti iwa ẹlẹyamẹya ti o pin si bi Mandela ṣe jade ninu ẹwọn lẹyin ọdun mẹtadinlọgbọn.

Àkọlé àwòrán,

Nelson ati Winnie Mandela nigbati o jade ninu ẹwọn ni ọdun 1990

Sibẹsibẹ, ipinya wa laarin Winnie ati Nelson Mandela lori ọrọ oṣelu ati ofin.

Awọn ẹbi rẹ yoo si atẹjade silẹ laipẹ lori iku rẹ.