Koko iroyin: Winnie Mandela d'agbere f'aye, Ìkọlu Boko Haram ni Màìdúgùri
Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.
Winnie Mandela di olóògbé lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin
Oríṣun àwòrán, AFP
Ibáṣepọ̀ Winnie àti ọkọ rẹ̀ dánmọ́rán bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ ara wọn sílẹ̀ ni 1996
Winnie Mandela, aya nígbà kan rí fún ààrẹ alawọ̀ dúdú àkọ́kọ́ ní orílẹ̀èdè South Africa ti papòdà lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin.
Winnie tọ́ jẹ́ gbajú-gbajà nínú ìgbéayé Nelson Mandela ṣi wà ní ọlọ́mọge nígbà tó di gbajúmọ̀ l'ágbo òṣèlú.
Ìjáfáfá rẹ̀ farahàn lásìkò tí ó di òpó òṣèlú tí ọkọ rẹ̀ gbékalẹ̀ mú nígbà tí wọ́n jù ú sí ẹ̀wọ̀n gbére ní 1964.
Boko Haram pa èèyàn 25 ní Màìdúgùri
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Boko haram tún ti s'oro ni Maiduguri
Àwọn ọmọ ikọ Boko haram tún ti s'oro ni Maiduguri, olú ìlú ìpínlẹ Borno, èyí tó ṣ'okùnfà ikú èèyàn mẹ́ẹ̀dógún tí àwọ̀n míràn tó dín díẹ̀ ni àádọ́rin sì farapa.
Ìròyìn fi ìdí rẹ múlẹ pé àwọn ọmọ ogun orílẹèdè Nàìjíríà pẹlú àwọn ọmọ ẹgbẹ adúnkùkùlajà Boko haram fìjà pẹẹta láwọn ìletò kan tí kò jìnà sí ìlú Maiduguri ni alẹ ọjọ àìkú. E ka ekunrere re ni bii
Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni
Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC
Fidio wa fun toni
Èkó: Àwọn akínkánjú obìnrín tó ń wa Márúwá
Èkó: Àwọn akínkánjú obìnrín tó ń wa Márúwá