Brymo: Oṣó ni mí, àjẹ̀ ni mí nítorí mo ní ìmọ̀ nípa ìjìnlẹ̀ orin

Brymo

Oríṣun àwòrán, @BrymOlawale

Àkọlé àwòrán,

Brymo ní ìfẹ́ ni ẹ̀sìn tí ó ga jùlọ

Gbajúgbaja òǹkọrin nì, Brymo Ọláwálé tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí 'Brymo' ti jẹ́wọ́ wí pé oṣó àti àjẹ ni òhun.

Gbajúgbaja òǹkọrin náà ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tó ṣe lórí ìkànnì ayélujára facebook ti BBC Yorùbá lọ́jọ́ ìṣẹ́gun.

Brymo ní ohun tó ṣeni láàánú jùlọ ni wí pé àwọn èèyàn ilẹ̀ adúláwọ̀ ti gbàgbé ìṣẹ̀mbáyé wọn pẹ̀lú ẹ̀sìn àbáláyé eléyí tó ní ó mú wọn gba ẹ̀sìn àjèjì tó ti wá sọ ayé di ìdàkudà báyìí.

Brymo

Oríṣun àwòrán, @BrymOlawale

Àkọlé àwòrán,

Brymo ní àwọn èèyàn ilẹ̀ adúláwọ̀ ti gbàgbé ìṣẹ̀mbáyé wọn

"Oṣó ni mí, àjẹ́ ni mí. Kò sí ìlú tí oṣó tàbí àjẹ́ kò sí. Ṣùgbọ́n mi ò mọ̀ nípa ti ẹlẹ́gbẹ́ dé o.

"Gẹ́gẹ́ bíi onímọ̀ nínú ìjìnlẹ̀ orin ìbìlẹ̀, mo leè pe ara mi ní oṣó orin."

Ìlúmọ̀ọ́ká akọrin náà ní, púpọ̀ wàhálà tí ó ń wáyé láwùjọ lóde òní ló jẹ́ wí pé ẹ̀sìn ló fàá.

Brymo

Oríṣun àwòrán, @BrymOlawale

Àkọlé àwòrán,

Ìfẹ́ nìkan ló leè to ayé báyìí níbi tí ẹ́sìn bàájẹ́ dé

Brymo ní púpọ̀ èdè-àìyedè, àìsí ìfẹ́ àti ìkọlù tó ń wáyé lórílẹ̀èdè Nàíjíríà loni ló jẹ́ wí pé àwọn tí wọ́n pe ara wọn ni ẹlẹ́sìn ló wà ní ìdí rẹ̀.

"Ohun dáradára tí ẹ̀sìn ń ṣe láwùjọ wa báyìí kò tó iṣẹ́ burúkú tí ó ń ṣe láwùjọ. Ìdí nìyẹn tí mo fi rìn jìnà sí ẹ̀sìn."

Ó ní ìfẹ́ ni ẹ̀sìn tí òun ń sìn báyìí nítorí ìfẹ́ nìkan ló leè to ayé báyìí níbi tí ẹ́sìn bàájẹ́ dé.

"Ohun tí a ń rí báyìí ni pé àwọn èèyàn ń ṣe ẹ̀sìn ṣùgbọ́n wọn kò ní ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìfẹ́ ló dára jù, ibi tí kò bá sí ìfẹ́ kò sí ẹ̀sìn. Kò dẹ̀ sí ìfẹ́ lorílẹ̀èdè Nàíjíríà lọ́wọ́ yíí."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: