Ọbásanjọ́: Ẹ má dìbò fún ìjọba aláròyé

Aworan Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Obasanjo ni awawi ijọba Buhari ti pọju.

Aarẹ ana lorilẹẹde Naijiria, Olusegun Obasanjo ti ni ki awọn ọmọ orilẹẹde yii mase dibo fun ijọba to wa lode bayii lọdun 2019.

Ọbasanjọ ke gbajare naa nigba to n gba alejo awọn ọmọ ẹgbẹ New Nigeria 2019 ni ile rẹ nilu Abẹokuta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ogundamisi: Ọbasanjọ ni ko jẹ k'awọn ọdọ de'po

Àkọlé fídíò,

Ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Ọjogbọn Wọle Soyinka

Obasanjo ni ki wọn mase jẹ ki ina eesi jo wọn lekeji pẹlu bi ijọba Buhari ti se ja ireti wọn kulẹ.

'Oun to daju ni pe,ti a ba ni ijọba ti ko ka oju osuwọn, gbogbo wa naa ni a dijo n faragba a. Ẹko akọkọ ti mo kọ ninu igbaradi ise ologun ni pe, o ko gbọdọ jẹki ina eesi jo ẹ lemeji. O ko gbọdọ fi asise rinle. Asise ni asise n je ,ko lorukọ meji''

Agba oselu naa tẹsiwaju pe, ẹgbẹ oselu APC ati PDP ko le gbe Naijiria de ebute ogo nitori wọn ti ja ireti awọn ọmọ orilẹẹde Naijiria kulẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn agbẹnusọ ijọba Buhari ni ọrọ Obasanjo ko jẹ tuntun

Ẹwẹ, olubadamoran pataki feto iroyin fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Femi Adesina ti fesi si ọrọ Aarẹ Obasanjo.

Buhari ni ọrọ Ọbasanjọ ko jẹ tuntun

Adesina ni agbeyẹwo ijọba awọn lati ọdọ Olusẹgun Obasanjo ''ko jẹ tuntun.''

Adesina kede ọrọ naa nigba to n ba ileese amounmaworan aladani kan sọrọ lori ẹro ibanisọrọ nipa ohun ti Obasanjo sọ.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Adesina tẹsiwaju pe, Minisita fun eto iroyin, Lai Mohammed ti fesi saaju si iwe ti Aarẹ Obasanjo kọ laipe yi .

O ni ijọba APC ''ko ni dake lori asise ti ijọba ana se lati le dẹkun irufẹ rẹ lọjọ iwaju.''