Ọ̀rọ̀ Dino Melaye: ọlọ́pàá mu afunrasí méjì tó sálọ

Asofin Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @dinomelaye

Àkọlé àwòrán,

Iléesẹ́ ọlọ́pàá ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà kéde pé òun ń wá sẹ́nètọ̀ tó ń sojú ẹkùn ìdìbò ìlà oórùn Kogí, Dino Mélayé

Ileeṣẹ ọlọpa ni ipinlẹ Kogi sọ pe oun yoo gbẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin Dino Melaye ati awọn afurasi ọdanran mẹrin lọ sile-ẹjọ giga ni Lokoja, Ipinle Kogi ni ọjọ kẹ̀wa oṣu karun ọ̀dun yii.

Awọn afurasi naa ni: Kabiru Seidu, Nuhu Salisu, Musa Mohammed ati Emmanuel Audu.

Awọn mẹrẹẹrin na papa bora lẹyin ti wn sa kuro ninu ahamọ agọ ọlọpa ipinlẹ Kogi ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹta ọdun yi, eyi ti o fa bi ga ọlọpa ṣe yọ Kọmisọna ọlọpa ipinlẹ naa niṣẹ.

Agbẹnusọ fun awọn agbofinro, Jimoh Moshood ti o ṣe ifitonileti ọrọ yi lakoko ti o n sọrọ pẹlu awọn oniṣẹ iroyin nilu Abuja lọjọ iṣẹgun sọ pe awọn ṣi n wa meji ninu awọn afurasi naa.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police

Àkọlé àwòrán,

Awon afunrasi mefa naa fẹsun kan Senato Dino Melaye wipe oun loun ran wọn ni iṣẹ

Awon afunrasi mefa naa fẹsun kan Senato Dino Melaye wipe oun loun ran wọn ni iṣẹ lati fa ijangbọn ni ipinlẹ naa ṣaaju idibo apaapọ ọdun 2019.

Ile iṣẹ ọlọpa Kogi lori itakun agbaye Twitter sọ wi pe awọn ti ri gbogbo awọn to fẹsẹ fẹẹ naa ati wipe awọn yoo gbe wọn lo si ile ẹjọ.

Laipe yii ni ajo ọlọpa agbaye, Interpol sọ wi pe awọn kii da si ọrọ oṣelu ilu ati wipe ki ajọ ọlọpa ṣe ofintoto to peye lori ọrọ naa.

Ijọba apapọ ti figba kan gbe sẹnatọ Dino Melaye lọ Ile-Ẹjo ti Ijọba apapọ to wa ni Abuja, lori ẹsun wipe o parọ fun awọn ọlọpa wipe, awọn kan fẹ gba ẹmi oun losu Kẹrin, Ọdun 2017.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: