Góòlù Sangalo: Àwọn èèkàn agbábọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa Ronaldo

Ronaldo ń gbá bọ́ọ̀lù
Àkọlé àwòrán,

Góòlù àwò dàmi ẹnu yíí kún ara góòlù méjì tí Ronaldo gbá wọlé nínú mẹ́ta tí Real Madrid fi ṣe àgbà Juventus

Cristiano Ronaldo, agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Real Madrid.

"Góòlù àwòdàmiẹnu ni, ọ̀kan lára àwọn góòlù tó dára jùlọ tí mo ti gbá wọlé láti ìgbà tí mo ti ń gbá bọ́ọ̀lù ni."

Skip Twitter post, 1

End of Twitter post, 1

Àkọlé àwòrán,

Ńṣe làwọn olólùfẹ́ Juventus dìde sókè rọ òjò àtẹ́wọ́ lu Ronaldo lẹ́yìn tó gbá góòlù náà wọlé

Zinedine Zidane, Olùkọ́ni ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Real Madrid.

"Góòlù tí Cristiano gbá wọlé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn góòlù tó dára jù nínú ìtàn bọ́ọ̀lù."

Skip Twitter post, 2

End of Twitter post, 2

Àkọlé àwòrán,

Góòlù àkẹ̀yìn sílé gbá tí Cristiano Ronaldo gbá wọlé ni ariwo rẹ̀ gbòde níbi ìwọnsẹ̀ tó wáyé láàrín Juventus àti Real madrid

Gary Lineker, agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbàkanrí.

"Mo ti ń rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn góòlù láti ìgbà tí mo ti d'áyé ṣùgbọ́n èyí kàmọ̀mọ̀."

Skip Twitter post, 3

End of Twitter post, 3

Àkọlé àwòrán,

Ronaldo tàn bí oòrùn níwájú Juventus

Micheal Owen, agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Liverpool, Real Madrid ati Manchester united nígbàkanrí.

"...góòlù rẹ̀ àkọ́kọ́ ko láfiwé. mi ò ní ọ̀rọ̀ tí mo lè fi ṣàkàwé góòlù rẹ̀ kejì."

Skip Twitter post, 4

End of Twitter post, 4

Àkọlé àwòrán,

"...mi ò ní ọ̀rọ̀ tí mo lè fi ṣàkàwé góòlù rẹ̀..."

Alvaro Arbeola, agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Real Madrid.

"Cristiano Ronaldo leè fi orí ilẹ̀ ayé sílẹ̀ báyìí láti lọ figagbága pẹ̀lú àwọn òòṣà. Ó ti ṣe ohun gbogbo tán pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ran ara."

Skip Twitter post, 5

End of Twitter post, 5

Àkọlé àwòrán,

"Christiano Ronaldo leè fi orí ilẹ̀ ayé sílẹ̀ báyìí láti lọ figagbága pẹ̀lú àwọn òòṣà"

Ruud Gullit, agbábọ́ọ̀lù lórílẹ̀èdè Holland tẹ́lẹ̀.

"Ọlọ́run mi o, Christiano, irú góòlù wo lèyí."

Skip Twitter post, 6

End of Twitter post, 6

Àkọlé àwòrán,

"Ń ṣe ni mo dìde dúró pariwo MAMMA MIA..."

Tancredi Palmeri, ara àwọ̀n tó wà ni pápá ìṣiré tí Ronaldo ti gbá góòlù náà wọlé.

"Ń ṣe ni mo dìde dúró pariwo MAMMA MIA, tí mo sì pàtẹ́wọ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí a jìjọ wà ní gbàgede oníròyìn láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú."

Àkọlé àwòrán,

"Góòlù tí Christiano gbá wọlé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn góòlù tó dára jù nínú ìtàn bọ́ọ̀lù"