Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Ìlasamàjà: Ẹ̀mí mẹ́ta bọ́, ọ̀pọ̀ farapa

Osise ile Ileeṣẹ ti o n risi iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Àkọlé àwòrán,

Wọn ti gbe awọn to farapa lo si ile iwosan

Ìjàǹbá ọkọ̀ kan tó wáyé ní àárọ̀ ọjọ́rú ní Ìlasamàjà ní ìlú Èkó mú ẹ̀mí èèyàn mẹ́ta lọ, tí ọ̀pọ̀ míì sì tún farapa.

Ijamba ọkọ naa la gbọ wi pe o ṣẹlẹ ni ibudo iwọkọ Ilasamaja loju ọna marose Apapa-Oshodi nigbati ọkọ akero ajagbe kan kọlu katako ipolowo nla kan, eyi ti o wo lu ọkọ akero kan.

Oríṣun àwòrán, TAJUDEEN Adesola

Àkọlé àwòrán,

Wọn ti gbe awọn to farapa lo si ile iwosan

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ to n risi iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, Adebayo Kehinde (Lasema) to si fi idi isẹle naa mulẹ so wi pe iṣẹlẹ ijanba yi da ẹmi awọn ọkunrin mẹta legbodo lẹsẹkẹsẹ.

O ṣalaye siwaju sii wipe awọn ọkunrin mẹta miran pẹlu obinrin mẹrin tun fara kaaṣa yanyan ti wọ̀n si ti gbe wọn lọ si ile iwosan fun itọju pipe.

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Àkọlé àwòrán,

Ara adugbo ati awọn arinrinajo pejọ nibi isẹlẹ naa

Atẹjade naa wipe ọga agba ileeṣẹ to n risi iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko (Lasema), Adebayo Tiamiyu n rọ̀ awọ̀n awakọ̀ lati ṣe jẹjẹ loju popo, ki wọn si bikita fun ere asapajude.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: