Gomina APC: Saa Oyegun ti dopin, a o ṣèpàdé gbogboogbò

Aare Buhari ati awon Gomina kan

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Buhari ṣèpàdé pelu awon gomina APC

Awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni awọn ti f'aramọ ero Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lori saa ti awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa yoo maa lo nigba ti wọn ba wa ni ipo.

Alaga awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Gomina Abdulaziz Yari to jẹ gomina ipinlẹ Zamfara nigba to n ba awọn oniroyin s'ọrọ wipe ofin ẹgbẹ naa ko faaye gba ki wọn fi kun saa adari ẹgbẹ, eyi ti Yari sọ wi pe, o wa ni ibamu pẹlu ofin Naijiria.

Ọgbẹni Yari sọ wi pe, ipade ti awọn ṣe pẹlu Aarẹ Buhari ni ọjọ iṣẹgun lo yọri si igbesẹ ti awọn gbe naa.

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Àkọlé àwòrán,

Awuyewuye wa lori saa alaga ẹgbẹ John Oyegun

Ti a ko ba gbagbe, Aarẹ Buhari ṣe ipade idakọnkọ pẹlu awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ti awọn gomina naa si kọ lati ba awọn oniroyin s'ọrọ lori abajade ipade naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: