Pasitọ ge ọmọ ijọ lori, sinku rẹ sinu ṣọọṣi nipinlẹ Ogun

Oríṣun àwòrán, The Punch
Oluwatobiloba Ipense jẹ oluṣọ ni Holy Gathering Evangelical Church of God, Papalanto ni Ewekoro
Ọwọ ṣikun awọn ọlọpa ipinlẹ Ogun ti tẹ arakunrin kan ti o jẹ oluṣọ agutan ni ile ijọsin kan ni agbegbe Ewekoro nipinlẹ Ogun, Oluwatobiloba Ipense wipe o bẹ ori arabinrin abilekọ kan ti o ge apa rẹ mejeeji pẹlu ki o too sin oku rẹ sinu ile ijọsin rẹ.
Oluwatobiloba Ipense jẹ oluṣọ ni ileejọsin Holy Gathering Evangelical Church ti o wa ni Papalanto, ni agbegbe ijba ibilẹ Ewekoro.
Kọmiṣọna fun ọlọpa ni ipinlẹ Ogun, ọgbẹni Ahmed Iliyasu ti o ṣe afihan afusari apaniyan yi ṣalaye wipe pasitọ naa pa ololufẹ rẹ lati fi ṣe aajo owo gẹgẹbi iwadi wọn ṣe sọ.
Oríṣun àwòrán, The Punch
Oluwatobiloba Ipense sinku arabinrin ololufẹ rẹ sinu ileejọsin rẹ
Ọgbẹni Illiyasu wipe arakunrin kan to roukọ rẹ n jẹ Adebola Saheed ta awọn lolobo nigbati wọn ko ri ẹgbọn rẹ, Raliat Sanni ti o jẹ ẹni ọdun márùndínlógójì pẹlu ọmọ marun nile mọ lati ọjọ kejilelogun oṣu kẹta ọdun.
O wipe "Ninu ọrọ rẹ, oluṣọ-aguntan yi jẹwọ pe oun pa arabinrin naa ati pe oun sin oku rẹ sinu ijo oun lẹhin ti o ti bẹ ori rẹ ati ọwọ rẹ mejeeji fun awọn idi ti o kọ lati sọ fun awọn ọlọpaa."
"Mo bẹ awọn eniyan lati maa ṣe akiyesi gbogbo awọn ti wọn ṣe alabapin pẹlu ati nigba gbogbo lati maa ṣe ayẹwo awọn ara adugbo wọn pẹlu loore-koore lati dẹkun irufẹ ijamba bayii lawujọ".
Oríṣun àwòrán, The Punch
Awọn ọlọpa hu oku arabinrin naa jade ninu ṣọọṣi
Ṣugbọn nigbati o n sọrọ pẹlu awọn oniroyin, afurasi naa sọ pe oun kii ṣe oun ni o pa arabinrin naa, o sọ pe ẹlomiran ni o ṣe ọṣẹ naa.
Bakanna ni afurasi yi ti o jẹ olukọ ni ile-ẹkọ giga aladani Methodist ti o wa ni Arigbajo, sọ pe wọn fi ipa mu oun darapọ mọ ẹgbẹ okunkun ni.