Afẹ́fẹ́ òjò líle ṣọṣẹ́ ní ìlú Ìlọrin nípinlẹ Kwara

Oríṣun àwòrán, Abdul Momoh
Afẹ́fẹ́ òjò líle ṣọṣẹ́ nípinlẹ Kwara
Afẹ́fẹ́ òjò líle ṣọṣẹ́ ní ìlú Ìlọrin ní àṣàalẹ́ ọjọ́ ìṣẹ́gun.Ọ̀pọ̀ olùgbé ìlú Ìlọrin ní ìpínlè Kwara, ẹkùn ààrin-gbùngbùn orílèèdè Nàìjíríà ni wọ́n ń kérora ọṣétí ìjì náà ṣe.Ọ̀pọ̀ òrùlé ilé ni atẹ́gùn òjò náà gbé lọ; tí àwọn òpó iná àti ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú pátákó ajúwe ọ̀nà pẹ̀lú wó lulẹ̀.
Pápá ìṣiré ìpínlẹ̀ Kwara tó wà ní àdúgbò Taiwo Road ló f'ara kááṣá ìjì líle náà jùlọ.
Oríṣun àwòrán, Abdul Momoh
Ọ̀kẹ́ àìmọye sì ni owó àwon ọkọ̀ àti pátákó ìpolówó ọjà tíigi wó lù lásìkò tí ìjì náà fi jà.
Ọ̀pọ̀ tì orí kó yọ ní bèbè ikú, pàápàá jùlọ àwọn awakọ̀ ṣàlàyé wí pé ǹkan bíi agogo mẹ́fà sí méje alẹ́ ni òjò tó fa ìjì líle náà bẹ̀rẹ̀.Ọ̀kẹ́ àìmọye sì ni owó àwon ọkọ̀ àti pátákó ìpolówó ọjà tíigi wó lù lásìkò tí ìjì náà fi jà.