Kókó ìròyìn t'òní: APC f'ẹnu kò lórí sáà Oyegun, ẹ̀mí mẹ́ta bọ́ nípìnlẹ̀ Èkó

Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.

Gomina APC: Saa Oyegun ti dopin, a o ṣèpàdé gbogboogbò

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Buhari ṣèpàdé pelu awon gomina APC

Awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni awọn ti f'aramọ ero Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lori saa ti awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa yoo maa lo nigba ti wọn ba wa ni ipo.

Alaga awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Gomina Abdulaziz Yari to jẹ gomina ipinlẹ Zamfara nigba to n ba awọn oniroyin s'ọrọ wipe ofin ẹgbẹ naa ko faaye gba ki wọn fi kun saa adari ẹgbẹ, eyi ti Yari sọ wi pe, o wa ni ibamu pẹlu ofin Naijiria.

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Ìlasamàjà: Ẹ̀mí mẹ́ta bọ́, ọ̀pọ̀ farapa

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Àkọlé àwòrán,

Wọn ti gbe awọn to farapa lo si ile iwosan

Ìjàǹbá ọkọ̀ kan tó wáyé ní àárọ̀ ọjọ́rú ní Ìlasamàjà ní ìlú Èkó mú ẹ̀mí èèyàn mẹ́ta lọ, tí ọ̀pọ̀ míì sì tún farapa Agbẹnusọ fun ileeṣẹ to n risi iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, Adebayo Kehinde (Lasema) to si fi idi isẹle naa mulẹ so wi pe iṣẹlẹ ijanba yi da ẹmi awọn ọkunrin mẹta legbodo lẹsẹkẹsẹ.. Ẹ ka ẹkunrẹrẹ ni bii.

Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni

Gbọ iroyin iṣẹju kan BB

Fidio wa fun t'oni

Ìsẹ́yìn: Ilé aṣọ òkè alárà ǹ barà

Àkọlé fídíò,

Ìsẹ́yìn: Ilé aṣọ òkè alárà ǹ barà