Èkìtì 2018: Ìpolongo ìdìbò gómìnà yóò bẹ̀rẹ̀ lóṣù kẹrin

Awon to n dibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Idibo si ipo gomina ipinlẹ Ekiti yoo waye lọjọ kẹrinla, Osu keje

Ajọ to n ṣe eto idibo lorilẹede Naijiria, Inec ti si ọna silẹ fun awọn olupolongo lati bẹrẹ si ni se ipolongo fun idibo si ipo gomina ipinlẹ Ekiti, eleyi ti yọ waye lọjọ kẹrinla, Osu keje, ọdun yii.

Ajọ Inec fi ọrọ yii lede ni Ọjọru, ni ilu Ado Ekiti, ti wọn si fi lede wipe ipolongo naa yoo bẹrẹ lọjọ Karundinlogun, Osu Kẹrin, ọdun yii.

Ajọ naa wa parọwa fun awọn ẹsọ alaabo lati fi ohun gbogbo ti o yẹ si ipo lati le jẹ ki idibo naa o lọ ni irọwọrọsẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Inec n parọwa fun awọn ẹsọ alaabo lati fi ohun gbogbo ti o yẹ si ipo

Aṣoju ajọ Inec ni ipinlẹ Ekiti, AbdulGaniy Raji rọ awọn eniyan lati lọ tete gba PVC wọn, ti yoo fun wọn ni anfaani lati dibo gẹgẹ bi ọmọ ipinlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: