$1bn fún ríra èèlò ìjagun: Ẹnu ọmọ Nàíjíríà kò dúró

Ààrẹ Muhammadu Buhar

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Ilé asòfin àgbà ló ti kọ́kọ́ tako lílo bílíọ́ọ́nù kan dọ́là fún ríra ohun èèlò ìjagun

Ẹnu àwọn ọmọ Nàíjíríà kò sìn lóríi bílíọ́ọ́nù kan dọ́là owó ohun èèlò ìjagun ti Ààrẹ Muhammadu Buhari fọwọ́sí fún ilééṣẹ́ ológun níbẹ̀.

Mínísítà fún ètò ààbò, Mansur Dan Alli, ẹni tó ṣíṣọ lójú ọ̀rọ̀ yìí fáwọn akọ̀ròyìn lópin ìpàdé àwọn ìgbìmọ̀ elétò ààbò Nàíjíríà tún ní Ààrẹ Muhammadu Buhari fọwọ́sí owó náà kí ètò ààbò leè fìdí múlẹ̀ láwọn agbègbè tí ètò ààbò ti mẹ́hẹ.

Àmọ́ṣáọ ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàíjíríà ló ti ń fi èrò ọkàn wọn hàn nípa ìgbésẹ̀ yìí láwọn ojú òpó ìkànsíraẹni lórí ìtàkùn àgbáyé.

Lérò Reno Omokri, "kò bá kúkú sàn kí Buhari ní òun fọwọ́sí bílíọ́ọ́nù kan dọ́là gẹ́gẹ́ bíì owó tí yóò mú kí wọn tètè dìbò yan òun sípò ní ẹ̀ẹ̀kejì.

Ojú òpó ìkànsíraẹni Twitter rẹ̀ lórí ìtàkùn àgbáyé ló ti sọ̀rọ̀ yìí.

Bákanáà ni gómìnà Ayọ̀délé Fayose ti ìpínlẹ̀ Èkìtì náà ti fi igbe bọnu lórí owó yìí.

Ó ní wọn kò níí lo owó yìí fún ohunkóhun ju ètò ìdìbò ọdún tó ń bọ̀ lọ fún ìpadàpọ̀ ààrẹ Buhari àtàwọn gómìnà ẹgbẹ́ òsèlú APC.

Akọ̀wé fún ètò ìròyìn fún gómìnà Fayose ló kéde èyí síta fáwọn akọ̀ròyìn, tí Fayose náà sì gbé ìkéde náà síta lójú òpó Twitter rẹ̀.

Sẹ́nétọ̀ Ben Murray-Bruce ní tirẹ̀ ṣàlàyé wí pé láì jẹ́ pé ẹ̀ka aṣòfin fi ọwọ́ síi owó náà, erémọdé lásán ni Ààrẹ Muhammadu Buhari àti ìjọba rẹ̀ ń ṣe.

Murray-Bruce ni òmìnira ẹ̀ka ìṣèjọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló wà lábẹ́ òfin orílẹ̀édé Nàíjíríà.