Ọmọ ìjọ Shia: Ẹ tú El Zak-zakky sílẹ̀ ní àhámọ́

Àwọn ọmọlẹ́yín aṣíwájú ìjọ mùsùlùmí Shia lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Sheikh Ibrahim El Zak-zakky tún ti ṣe ìwọ́de Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Lọ́dún 2015 ni àwọn ológun mú Sheikh Ibrahim El Zak-zakky àti ìyàwó rẹ̀

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọlẹ́yín aṣíwájú ìjọ mùsùlùmí Shia lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Sheikh Ibrahim El Zak-zakky tún ti ṣe ìwọ́de kiri olú ìlú Nàìjíríà, Àbúja, láti bèèrè fún ìtúsílẹ̀ olórí ẹ̀sìn náà.

Àwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ ìlú kan náà darapọ̀ mọ́ àwọn olùwọ́de yíí làti bèèrè fún ìtúsílẹ̀ Sheikh Ibrahim El Zak-zakky, tí ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀èdè Nàìjíríà ti fi sí àhámọ́ láti ọdún méjì àbọ̀ sẹ́yìn, 2015.

Wọ́n ni o yẹ kí ìjọba bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ aṣíwájú ìjọ mùsùlùmí Shia lórílẹ̀èdè Nàìjíríà náà.

Gbàgede Eagle square làwọn olùwọ́de náà fi ìpàdé sí lọ́jọ́ọ̀rú, níbi tí wọ́n ti dí gbogbo ọ̀nà tó wọ iléeṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba nilu Abuja pa, eléyí tó dá súnkẹrẹ fà kẹẹrẹ ọkọ̀ sílẹ̀ fún àwọn awakọ̀ tó ń lọ sí àringbùngbùn ìlú Àbújá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEbenezer Obey: Ọjọ́ ìbí 76 tó ọpẹ́ fún Ọlọ́run

Wọ́n ní àwọn ọlọ́pàá ti dí wọn lọ́wọ́ ọ lílo ibùdó tí wọ́n máa ń lò tẹ́lẹ̀ ló mú wọn dojúkọ gbàgede náà.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ rèé tí àwọn alátìlẹyìn Zak-zakky yóò sèwọ́de

Àwọn olùwọ́de náà ti kọ́kọ́ wọ ìyáàjà pẹ̀lú àwọn agbófinró lásìkò ìwọ́de wọn lóṣù kínní ọdún 2018.

Lọ́dún 2015 ni àwọn ológun mú Sheikh Ibrahim El Zak-zakky àti ìyàwó lásìkò tí wọ́n ṣíjú sí ikọ̀ náà nínú èyí tí wọ́n ti pa àwọn ọmọ ìjọ mùsùlùmí náà tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún.