Sierra leone: Maada Bio di ààrẹ tuntun ni Sierra Leone

Ẹgbẹ́ òṣèlú APC lórílẹ̀èdè Sierra Leone ti pàdánù àtúndì ìbò ààrẹ lórílẹ̀èdè náà pèlú bí wọn ti ṣe kéde Julius Maada Bio gẹ́gẹ́bí ààrẹ tuntun níbẹ̀.

Maada Bio láti ẹgbẹ́ òṣèlú SLPP ni wọn ti búra fún báyìí lẹyìn tó borí ààrẹ Samura Kamara ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC, nínú àtúndì ìbò ààrẹ tó wáyé lọ́jọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n.

Àkọlé àwòrán,

Maada Bio láti ẹgbẹ́ òṣèlú SLPP ni wọn ti búra fún wọn báyìí gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ tuntun

Ẹgbẹrun méjìléláàdọ̀rún ìbò ní Julius Maada Bio fi já ààrẹ Samura Kamara sílẹ̀, lẹ́yìn tó ni mílíọ̀nù kan àti ọ̀ọ́dúnrún, tí ààrẹ Samura Kamara sì ní ìbó mílíọ̀nù kan àti igba ó lé díẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Julius Maada Bio ni yóò jẹ́ ààrẹ kaàrún fún orílẹ̀èdè Sierra Leone, lẹ́yìn tí àjọ elétò ìdìbò orílẹ̀èdè náà ti buwọ́lu èsì ìbò náà.

Ajagunfẹ̀yìntì ni Julius Maada Bio, ó sì tí fi ìgbàkanrí jẹ olórí ìjọba ológun lórílẹ̀èdè náà.