Àwọn agbébọn pa ọlọ́pàá méjì nígbàtí wọ́n kọlu àgọ́ ọlọ́pàá kan ní Kogi

Ìbọn atamátàsé AK-47
Àkọlé àwòrán,

Ìbọn atamátàsé AK-47 làwọn agbébọn náà fi di ìhámọ́ra ìjà tí wọ́n sì ń yìnbọn sókè kíkankíkan láti lé àwọn èèyàn jìnnà lásìkò ìkọlú náà

Kò dín ní ọlọ́pàá méjì pẹ̀lú aráàlú kan là wọ́n agbébọn ti ṣekúpa nígbàtí wọ́n kọlu àgọ́ ọlọ́pàá kan ní ìpínlè Kogi lẹ́kùn ààrin-gbùngbùn orílèèdè Nàìjíríà.

Àwọn agbébọn náà tó máàrún níye nígbà tí wọ́n kọ̀lú àgọ́ ọlọ́pàá náà ní agogo méjì òru ọjọ́ ìṣẹ́gun tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀.

Ọlọ́pàá méjì pẹ̀lú afunrasíkan tó wà láhámọ́ ni wọ́n pa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Ìròyìn sọ wí pé ìbọn atamátàsé AK-47 làwọn agbébọn náà fi di ìhámọ́ra ìjà tí wọ́n sì ń yìnbọn sókè kíkankíkan láti lé àwọn èèyàn jìnnà.

Àkọlé àwòrán,

Ikọ̀ Boko haram ti kọlu ìpínlẹ̀ Kogi lọ́pọ̀ ìgbà

Lẹyìn èyí ni wọ́n wọ àgọ́ ọlọ́pàá náà lọ láti pa awọn ọlọ́pàá àtí afunrasí náà.

Kòsí ẹni tó lè sọ ní pàtó ohun tó ṣokùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣùgbọ́n ìròyìn sọ pé àwọn agbébọn náà gbe ìbọn kan lọ pẹ̀lú àwọn ọta ìbọn.

Agbẹnusọ ilééṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlè Kogi, Willy Aya ṣàlàyé fún BBC pé ìwádìí ti bẹ̀rẹ ̀ lórí ìkọlù náà.

Ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ikọ̀ Boko haram ti kọlu ìpínlẹ̀ Kogi pàápàá jùlọ ní ìlú Okenne.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: