Ẹgbẹ́ Dókítà: A yóò máa kẹ́yin s'awọ̀n alárùn lassa

Ekute n jẹ koriko
Àkọlé àwòrán,

Dokita mẹjọ lo ti ba arun lassa lọ ni Naijiria

Àjọ tó ń gbógunti àjàkálẹ̀ ààrùn àti ìdènà rẹ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, ti kéde wí pé ìpínlẹ̀ tótó ogún ni àrun ibà Lassa ti wọ bayii lorilẹede Naijiria.

Ijọba apapọ àti ile ìgbimọ asofin agba si ti nṣisẹ lati dẹkun iba lassa lorilẹede Naijiria.

Pẹlu eyi, ẹgbẹ awọn dokita oníṣegun oyinbo lorilẹede Naijiria ti fi ikilọ sita bayii pe, bi ijọba ko ba gbe igbesẹ lati daabo bo awọn dokita kaakiri ileewosan, ko si igba ti awọn dokita lorilẹede Naijiria ko ni maa kẹyin si awọn alaisan ti wọn ba funra si wi pe wọn ni arun Iba Lassa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita iṣegun lorilẹede Naijiria, Dokita Mike ogirima ni "Ko si bi awọn dokita ko ṣe ni kọ ipakọ si awọn alaisan to ba wa fun itọju aisan iba lassa ni ileewosan gbogbo, nitori ijọba ko tii ṣe ohun to kun oju oṣuwọn lori aisan naa."

Bakanaa lo tun fi idi rẹ mulẹ pe ko din ni dokita mẹjọ to ti ku nipasẹ arun iba lassa bayii, eleyi to ni ko yẹ ko ri bẹẹ ka ni ohun eelo idaabobo to peye wa fun awọn dokita atawọn osisẹ eleto ilera yoku ni.

Ile asofin agba buwọlu ofin SADC lati gbogun ti ọwọja arun Lassa

Amọṣa, minisita fun eto ilera lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Isaac Adewọle ni, ijọba orilẹede Naijiria n sa ipa gidigidi lati dẹkun ọwọja arun naa.

Ọjọgbọn Adewọle ni, ajọṣepọ ti waye pẹlu awọn ajọ eleto ilera lagbaye lati kani ọwọja arun naa nilẹ.

Ijọba apapo ti pese owo fun eto ilera, bee ni ileegbimọ asofin agba naa ti buwọlu ofin SADC lati gbogunti ọwọja arun lorilẹede yii."

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ijọba apapọ àti ileegbimọ asofin agba ti nṣisẹ lati dẹkun iba lassa

Minisita feto ilera ni, ifowosowopo pelu awọn ipinlẹ gbogbo se pataki lati kawọ arun naa nilẹ.

Gẹgẹbii abajade iroyin kan lati ọdọ ajọ to n mojuto igbogunti arun lorilẹede Naijiria, eeyan mejilelogoje lo ti ba arun iba lassa lọ lorilẹede Naijiria lati ibere ọdun 2018.

Bakanna lo ni awọn ipinlẹ ti arun naa ti rinlẹ julọ ni Edo, Ondo, ati Ebonyi.