PDP: A kò mọ nǹkan tí Buhari fẹ́ẹ́ fi bílíọ̀nù dọ́là kan ṣe

Aworan ọmọogun Naijiria
Àkọlé àwòrán,

Ija ileese ọmọogun Naijiria pẹlu Boko Haram ti n sunmọ ọdun mẹjọ bayi

Ẹgbẹ oṣelu PDP lorilẹẹde Naijiria ni ọgbọn alumọkọrọyi ni ẹgbẹ APC fẹ da pẹlu bi Aarẹ Buhari ti ṣe fọwọsi nina owo iya biliọnu dollar kan fun aabo ilu.

Igbakeji alukoro ẹgbẹ PDP, Diran Odeyemi lo lede ọrọ naa nigba ti o'n fesi si ikede Minisita fun eto abo, Mansur Dan Ali lori aṣẹ ti Aarẹ Buhari pa nipa nina owo yii.

O ni ''owo oṣelu ni. Ko si Boko Haram kankan ti wọn fẹ fi ba ja. Sẹbi wọn lawọn ti bori Boko Haram ni? Kini wọn wa fẹ fi aduru owo yii ṣe?''

O tẹsiwaju pe ile igbimọ aṣofin ni lati tọ pinpin bi Aarẹ Buhari ko ṣe gba aṣẹ ko to o buwọ lu nina owo naa.

A ko ri anfaani owo ti ijọba n naa

Onimọ nipa eto inawo kan, Shuaibu Idris, ninu ọrọ ti rẹ ni ki a to le sọ boya ijọba lẹto lati naa owo iya biliọnu kan naa tabi ko lẹto, o yẹ ki a ṣe agbeyẹwo iye ti ijọba ti naa sẹyin lori pipese aabo fun ara ilu.

Àkọlé àwòrán,

Ijọba ni owo naa wa fun kikoju ipẹnija agbesunmọmi Boko Haram

O ni lootọ ni pe ijọba ti ṣe aṣeyọri nipa kikoju Boko Haram ṣugbọn anfaani owo ti wọn naa ko han lara pipese ohun ija tabi iwuri fun awon ọmọ ogun.

Irinajo owo iya biliọnu dọla naa

  • Lọjọ kẹrinla osu kejila ọdun 2017 ni Gomina Godwin Obaseki ti ipinle Edo fi to awọn akoroyin leti pe ajọ to gajulọ lori ọrọ aje lorilẹẹde Naijiria ti pinu lati naa biliọnu dollar kan ninu asuwọn to rẹgun ninu akoto owo epo rọbi lati fi pese abo fun ara ilu.
  • Ni osu kejila ọdun kan naa,ile asofin agba ni ki Aarẹ Buhari ma se na owo naa lai gba iyanda lati ọdọ ile asofin.
  • Gomina Ayodele Fayose ti ipinlẹ Ekiti fagbeta pe ohun o si lara awọn Gomina to fi ọwọ si nina owo iya milionu dollar kan. O ni wọn fẹ lo owo naa fun ipolongo idibo Aarẹ Buhari lọdun 2019 ni.
  • Losu keji ọdun 2018, awuyewuye waye laarin awọn ọmọ ile igbimọ asoju sofin lori nina owo naa.
  • Lọjo kẹrin osu kẹrin, ọdun 2018, Minista fun eto abo, Mansur Dan Ali kede pe Aarẹ Buhari ti fọwọ si nina owo biliọnu dollar kan fun rira ohun ija fun ileese ologun lati le daabo bo ilu.

O jọ gate ko jọ gate

Lọdun 2014, bi idibo Aarẹ orilẹẹde Naijiria ti se n sunmo bo ni Aarẹ ana, Goodluck Jonathan, gba iyanda lati ọdọ ile igbimọ asofin lati ya biliọnu dollar.

O ni owo naa wa fun kikoju ipẹnija agbesunmọmi Boko Haram.

Senator Ahmed Makarfi to jẹ alaga igbimọ ọrọ isuna ninu ile nigba naa ni wọn yoo fi owo naa ra ''baalu,ọkọ oju omi ati ohun ija miran''

Asẹyinwa ọrọ naa ni ẹsun ikowoje ti ijọba Buhari fi kan Alamọran fun eto aabo tẹlẹri, Sambo Dasuki ati awọn ọmọ orilẹẹde yi miran.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: