Àwọn aláboyún f'ẹ̀hónú hàn lórí owó ìgbẹ̀bí ní ìpínlẹ̀ Òǹdó

Ile-iwosan Alamọja ti ijọba ipinle Ondo
Àkọlé àwòrán,

Awon aboyun nfe ki Gomina rotimi Akeredolu yi ofin yi pada

O kere tan, o to ọgọrun aboyun to rọ lọ si Ile-iwosan Alamọja ti ijọba ipinle Ondo nilu Akure ni Ojobo lati fẹhonu han lori awọn idiyele giga fun awọn itọju ati igbẹbi fun alaboyun ni ile iwosan naa.

Awọn obinrin aboyun, ti wọn ti ile-iwosan naa pa ṣe apejuwe awọn owo ti wọn n gba nile iwosan naa bi ohun ibanujẹ ati pe ojẹ ohun irẹjẹ fun ọpọlọpọ ninu wọn.

Awọn alaboyun naa npe akiyesi Gomina ipinlẹ Ondo, arakunrin Rotimi Akeredolu si ọrọ naa wipe ki o yi ofin naa pada.

Àkọlé àwòrán,

Awọn alaboyun f'ẹhonu han lori owo igbebi ni Akure

Diẹ ninu awọn alaboyun naa, ti wọn sọrọ pẹlu awọn oniroyin, ṣe akojọ awọn idiyele bi: ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn, (N25,000) fun igbẹbi alagboyun, ẹgbẹrun lọna aadọta (N50,000) fun ṣiṣe iṣẹ abẹ (Caesarean Section) ati awọn kẹ aimọye oriṣiriṣi owo ainidi laarin ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta naira si ẹgbàajì naira.

Wọn tun fi ẹsun kan awọn aṣoju ile-iwosan naa wipe wọn n gba awọn owo ele yii "gẹgẹ bi aṣẹ ti ijoba ipinlẹ pa fun wọn."

Àkọlé àwòrán,

Wọn ti ilẹkun abawọle si ile iwosan naa pa fun ọpọlọpọ wakati

Pẹlu ibinu, awọn obinrin naa ṣe aridaju wipe wọn gbe ilẹkun iytana igbẹbi ile iwosan naa ti pa lakoko ifẹhonu han yii ati pe wọn tun ti ilẹkun abawọle si ile iwosan naa pa fun ọpọlọpọ wakati.

Komisona fun eto ilera ni ipinle naa, Wahab Adegbenro gbiyanju lati parọwa fun awọn obinrin naa lati dẹkun ifẹhonuhan yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: