Ilé ẹjọ́ Èkìtì d'ájọ́ ikú f’ọ́kùnrin tó jí ọtí méje áti páálí sìgá

Ohun ti won fi npa awon eniyan
Àkọlé àwòrán,

Ìgò ọtí méje àti sìgá ṣokùnfà ẹjọ́ ikú

Ọkunrin kan ni ipinlẹ Ekiti, lorilẹede Naijiria ti ri idajọ iku he lẹyin to ji ọti ẹlẹrin dodo meje ati paali siga kan.

Ninu idajọ ti wọn gbe kalẹ ni ile ẹjọ giga to wa ni Ekiti, adajọ to pe orukọ ẹni ti wọn f'ẹsun kan naa gẹgẹ bii Babatunde jẹbi ẹsun ole jija ati nini ada ati okọ nigba ti wọn mu u wipe o jale.

Adajọ ni iku ki wọn ye igi fun ni Babatunde yoo ku, nitori wipe o pẹlu awọn adigunjale mẹrin kan ti wọn tun gba foonu alagbeka oniyebiye lọwọ awọn eniyan.

Àkọlé àwòrán,

Ilé ẹjọ́ Èkìtì d'ájọ́ ikú f'ọ́kùnrin tó jí ọtí méje áti páálí sìgá

Amọ, idajọ iku naa ti fa ọpọlọpọ ariyanjiyan laarin awọn ọmọ orilẹede Naijiria, ti awọn miran si n pe fun idajọ iku fun awọn oselu ti wọn n lu owo ilu ni ponpo ati awọn asebajẹ lawujọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: