Kókó ìròyìn t'òní: Ìdájọ́ ikú ní Èkìtì, Aláboyún f'ẹ̀hónú hàn l'Òǹdó
Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.
Àwọn aláboyún f'ẹ̀hónú hàn lórí owó ìgbẹ̀bí ní ìpínlẹ̀ Òǹdó
Oríṣun àwòrán, Aproko Girl
Awọn alaboyun f'ẹhonu han lori owo igbebi ni Akure
O kere tan, o to ọgọrun aboyun to rọ lọ si Ile-iwosan Alamọja ti ijọba ipinle Ondo nilu Akure ni Ojobo lati fẹhonu han lori awọn idiyele giga fun awọn itọju ati igbẹbi fun alaboyun ni ile iwosan naa.
Awọn obinrin aboyun, ti wọn ti ile-iwosan naa pa ṣe apejuwe awọn owo ti wọn n gba nile iwosan naa bi ohun ibanujẹ ati pe ojẹ ohun irẹjẹ fun ọpọlọpọ ninu wọn.
Ilé ẹjọ́ Èkìtì d'ájọ́ ikú f'ọ́kùnrin tó jí ọtí méje áti páálí sìgá
Oríṣun àwòrán, Erik S. Lesser/Getty
Ìgò ọtí méje àti sìgá ṣokùnfà ẹjọ́ ikú
Ọkunrin kan ni ipinlẹ Ekiti, lorilẹede Naijiria ti ri idajọ iku he lẹyin to ji ọti ẹlẹrin dodo meje ati paali siga kan.
Ninu idajọ ti wọn gbe kalẹ ni ile ẹjọ giga to wa ni Ekiti, adajọ to pe orukọ ẹni ti wọn f'ẹsun kan naa gẹgẹ bii Babatunde jẹbi ẹsun ole jija ati nini ada ati okọ nigba ti wọn mu u wipe o jale. Ẹ ka ẹkunrẹrẹ rẹ ni bii.
Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni
Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC
Fidio wa fun toni
Màmá Boko Haram: Leah yóò padà sílé láì s'éwu
Boko Haram yóò dá Leah sílé