Ìkọlù Benue: Ẹ̀mí 24 tún bọ́ sọ́wọ́ darandaran

Àwọn màálù àti darandaran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀pọ̀ òkú ló ti sùn láti ọwọ́ darandaran

Àwọn asojú-sòfin láti ìpínlẹ̀ Benue ti ké gbàjarè lórí àkọ̀tun ìkọlù darandaran tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ náà.

Ipe naa waye lọ́jọ́bọ níbi ìjókòó ilé asòfin àpapọ̀ ní ìlu Abuja.

Wọn bèèrè pé káwọn ọmọogun máa wà ní sẹpẹ́ láwọn agbègbè tí ìkọlù ti máa ń wáyé lemọ́lemọ́.

Bákannáà ni wọ́n ń bèèrè pé kí ìjọba àpapọ̀ kéde àwọn darandaran gẹ́gẹ́ bíi adúnkookò mọ́ni nítorí pé ó lé ní ẹ̀mí èèyàn mẹ́rìnlélógún míì tó tún bọ́ sọ́wọ́ àwọn afurasí darandaran naa lásìkò àkọ̀tun ìkọlù míì tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Benue lọjọ́ kejì àti ìkẹrin osù kẹrin, bẹẹ si ni ọ̀pọ̀ èèyàn tún ti di àwátì.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ojoojumọ ni ẹmi ọpọ eeyan nbọ ninu ikọlu awọn darandaran lorilẹede Naijiria

Àwọn asojú-sòfin náà tún wá ń kọminú lórí bí wọn se fòpin sí ìgbàródan àwọn ológun nínú isẹ́ Operation Cat Race ni ìpínlẹ̀ Benue, nígbàtí wọ́n fi ọ̀sẹ̀ díẹ̀ kún ìgbàródan àwọn ológun náà ní ìpínlẹ̀ Taraba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nígbà tó ń gbarata lórí ìsẹ̀lẹ̀ yìí, Asòfin Dickson Takighir sọ pé agbègbè Ikyon, Semaka, Asom, Babanruwa, Udei, Umenger àti Agasha ni wọ́n kọlù, sùgbọ́n àwọ́n darandaran náà, tí ẹnu kò sìn lára wọn náà, tún ti gẹ̀gùn sí Nzorov, nígbaradì láti kọlu Gbajimba, tó wà níjọba ìbílẹ̀ Guma.

A fẹ́ kí àwùjọ àgbáyé dìde láti ràn wá lọ́wọ́

"Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọ́n agbégbọn darandaran náà ti gbàkóso agbègbè Sengev, Mbakyondo àti Mbapa, a sì ń késí ìjọba àpapọ̀ àti àwùjọ àgbáyé láti dìde sí ọ̀rọ̀ yìí, kó tó bọ́wọ́ sórí."

Bákannáà ni wọ́n ń fẹ́ ètò ìrànwọ́ tó péye fún àwọn èèyàn tí kò nílé lórí mọ́ ní ibùdó ogunléndé tó wà ní ìpínlẹ̀ náà.