Ìṣẹ̀lẹ̀ Èkó: Aáwọ̀ Ọbàkan sọ ilé di áláwọ̀ méjì

Àkọlé fídíò,

Ìṣẹ̀lẹ̀ Èkó: Aáwọ̀ Ọbàkan sọ ilé di áláwọ̀ méjì

Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fáwọn èèyàn tó ń kọjá ní àdúgbò Bámgbóṣé, lágbègbè Lagos Island nílùú Èkó nítorí ilé alájà méjì yìí tó wà lágbègbè náà, tó jẹ́ abala méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ilé náà, tí kò dín ní àádọ́ta ọdún, la gbọ́ pé ẹni tó nií ti kú.

Àmọ́ṣá ṣe wọ́n ní bí iná bá kú, yóò fi eérú bojú, èyí ló mú àwọn ọmọ rẹ méjì, tí wọn jẹ́ ọkùnrin àti obìnrin, jogún ilé náà.

Ilé yìí sàfihàn pé ààrin àwọn tó ni kò gún

Lẹ́yìn aáwọ̀ tó wáyé láààrín wọn. kí wọn tó pín ilé náà fún wọn, ó fojú hàn gbangba pé ààrin àwọn ọmọ tó jogún ilé náà kò gún.

Ń ṣe ni wọ́n fi òpó kan pín ilé náà sí méjì níwájú, tí wọ́n tún apákan se, tí wọn sì fi apá kejì sílẹ̀ sí ipò àtijọ́ tó wà tẹ́lẹ̀.

Àkọlé àwòrán,

Bí ilé yìí se rí kò se àkóbá fún àwọn ayálégbé ibẹ̀.

Lásìkò àbẹ̀wò BBC Yorùbá sí ilé yìí ládúgbò Bámgbósé, a gbọ́ pé èyí obìnrin ló mú apá òsì ilé náà, nígbàtí ọkùnrin mú apá ọ̀tún.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn ayálégbé tó bá wa sọ̀rọ̀ ni, ẹnu àwọn ọmọ náà kò ṣọ̀kan lórí ilé yìí, bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ èyí obìnrin rí jájẹ ju ti ọ̀kùnrin lọ̀.

Iẹ́ kò ní pẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lórí abala kejì ilé náà

Abala tí wọn sì túnṣe yìí jẹ́ ti obìnrin nígbàtí abala tí kò rí àtúnṣe náà jẹ́ ti ọkùnrin.

Àwọn ayálégbé inú ilé náà ní, bí ó tilẹ̀ jẹ́pé ààrin àwọn ọmọ tó jogún ilé náà kò gún, síbẹ̀ èyí kò ní ipa kankan lórí àwọn, pẹ̀lú àfikún pé, isẹ́ kò níí pẹ́ bẹ̀rẹ̀ ní abala kejì ilẹ́ náà.

BBC Yorùbá tiẹ̀ gbọ́ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti dásí ìsẹ̀lẹ̀ náà.