Aáwọ̀ PDP Ọ̀sun: Igun Omisore dáná sun àṣíá ẹgbẹ́

Ọmọ ẹgbẹ́ PDP kan ń dáná sun àṣíá ẹgbẹ́ òṣèlú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP

Oríṣun àwòrán, Toba Adedeji

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP kan nípínlẹ̀ Ọ̀ṣun dáná sun àṣíá ẹgbẹ́ òṣèlú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP

Igun ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kan nípínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti dáná sun àṣíá ẹgbẹ́ òṣèlú náà gẹ́gẹ́bíi ara ọ̀nà láti fi ẹ̀hónú wọn hàn sí bí nǹkan ṣe ń lọ sí, nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà.

Igun tó dáná sun àṣíá ẹgbẹ́ náà ló jẹ́ tàwọn tó jẹ́ olólùfẹ́ aṣíwájú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, ẹni tó tún ti fìgbàkanrí jẹ igbákejì Gómìnà àti sẹ́nétọ̀ ní ìpínlè Ọ̀ṣun, Iyìọlá Omíṣoore.

Oríṣun àwòrán, Toba Adedeji

Àkọlé àwòrán,

Dúkùú abẹ́nú lo ń da omi àláfíà ẹgbẹ́ PDP rú ní Ọ̀sun

Dúkùú lórí bóyá kí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbé àṣíá olùdíje ipò Gómìnà fún Omíṣoore ti ń wáyé ṣáájú àkókò yíí, kí wọn tó yọ ọwọ́ rẹ̀ láwo nínú àwọn alẹ́núlọ́rọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú náà pẹ̀lú ètò ìdìbò láti yan ìgbìmọ̀ ìṣàkóso ẹgbẹ́ òṣèlú náà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ni oṣù tó kọjá.

Gbogbo àṣíá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó wà níwájú iléeṣẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú náà ní agbègbè Ògo Olúwa ní ìlú Òṣogbo ni wọ́n dáná sun, ki sẹnetọ̀ Omíṣoore tó léwájú ìpàdé pèlu àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Toba Adedeji

Àkọlé àwòrán,

Gbogbo àṣíá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó wà níwájú iléeṣẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú náà ní agbègbè Ògo Olúwa ní ìlú Òṣogbo ni wọ́n dáná sun

Àmọ́ṣá, àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlè Ọ̀ṣun ti sọ pé, kò yẹ kí Sẹ́nétọ̀ Omíṣore fi ìwàǹwara lábẹ̀ gbígbóná, kó sì tún rántí pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP yí kan náà ló rán an lọ sí ilé aṣòfin àgbà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kò yẹ kí Omisore bọ́ sí pańpẹ́ ẹgbẹ́ PDP

Alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Sọjí Adágúnodò, nínú àtẹ̀jáde kan ní, "kò yẹ kí Omíṣore bọ́ sínú ìkẹkùn ẹgbẹ́ òṣèlú APC"

Ṣùgbọ́n Omíṣore ti sọ pé, òun kò ní ibií lọ àtipé, digbí lòun ṣì wà lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP.