Ẹ̀sùn ìkówójẹ: Jacob Zuma yóò fojú winá òfin

Jacob Zuma, aarẹ South Africa ana àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

L'oni ni wọn yoo bẹrẹ igbẹjọ Jacob Zuma lori ẹsun iwa ibajẹ

Ààrẹ South Africa tẹ́lẹ̀ri, Jacob Zuma, yóò fojú ba ilé ẹjọ́ lónìí lorí ẹ̀sun ṣiṣé owó ìlú báṣú-bàṣú lori òwo ńǹkan ìjà bílíọ́nù méjì-àbọ̀ dọ́là ni àwọn ọdún 1990.

Lara àwọn ẹ̀sun mẹrìndínlógún ti wọn yóò fi kan an, ni ìwà ìbàjẹ, jìbìtì àti kíkówó jádé lọ́nà àìtọ, èyí tó ń wáyé nile ẹjọ̀ ńlá kan ni ìlú Durban.

O ṣeéṣẹ́ ki ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ gba àsìkò gbọ́ọ́rọ́, pàápàá ní báyìí ti àwọn eeyàn fẹ bẹ̀rẹ̀ ìjà lori bóyá ki ìjọ̀ba maá san owó ìgbẹjọ́ Zuma lọ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

Ìgbẹ́jọ́ Zuma jẹ́ ẹ̀rí pé ìjọba alágbádá fìdí múlẹ̀ ní South Africa

Àwọn olọ́pá ń gbárádì fún ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn álátìlẹyìn ààrẹ orílẹ̀èdè náà tẹlẹ̀ri, ti wọn ti ṣé ìlérí pe àwọn yóò ṣe ìwọde lọ si ilé ẹjọ́ náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Orin idanimọ South Africa.

Akọ̀ròyìn BBC, Andrew Harding, sọ wipe, kí ààrẹ orilẹ̀ẹde náà tẹ́lẹ̀rí fi ojú ba ilé ẹjọ́ yóò jẹ ńǹkan ńlá fún ìjọba àwá-arawá ní South Africa.

O sọ wipe òpọ̀ yóò ri ìgbesè náà gẹgẹ bi òpin ṣiṣẹ̀ s'ofin lai ni ìjìyà.