Ilé ìwòsàn Àkúrẹ́ lorí ìfowó kun owó ìbimọ

Ilé ìwòsàn Àkúrẹ́ Image copyright APROKO GIRL

Olùdarí ilé ìwòsàn ìjọbá Àkúrẹ́, dókítà Moses Adewọle, tí sàlàyé pe òwọn gógó ńǹkan lo faá ti wọn fi fi owó kun owó ìgb'ẹ̀bi.

Olùdarí ilé ìwòsàn náà sọ wipe ìwọdẹ́ ti àwọn aláboyún ṣe ni Ọjọ́bọ̀ (Thursday) ní àpẹrẹ òṣelù nínú.

Díẹ̀ nínù àwọn aláboyún náà, ti wọn sọ̀rọ̀ pẹlu àwọn oníròyìn, ṣe àkojọ́ awọn ìdiyelé náà bií: ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹdọ́gbọ̀n, (N25,000) fún ìgbẹ̀bi alábóyún, ẹgbẹ̀rún lọná aádọ́tá (N50,000) fún ṣiṣé iṣẹ́ abẹ́ (Caesarean Section) àti àwọn òkẹ aìmọye oríṣiríṣi owó aìnídí láàárín ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta naira si ẹgbàajì naira.

Image copyright Aproko Girl
Àkọlé àwòrán Awọn alaboyun f'ẹhonu han lori owo igbebi ni Akure

Àwọn alábóyún náà pe àkiyèsí gomìnà ìpinlẹ Ondo, Rótìmi Ákérédolú, sí ọ̀rọ̀ náà wipe ki o yí òfín náà padà.

Dókítà Adewọle sọ wipe wọn fi owó kun owó ìforukọ́ silẹ̀ fun àwọn alábọyún látí N2,500 si N4,000 ni nitori àti dí ònà owó ẹ̀yìn fún àwọn òṣìṣẹ.

Image copyright Aproko Girl
Àkọlé àwòrán Wọn ti ilẹkun abawọle si ile iwosan naa pa fun ọpọlọpọ wakati

Sùgbọn nigba ti wọn bi lere iye ti wọn ń gba gẹgẹ bìí owó ìgb'ẹ̀bí tẹlẹ̀, o sọ wipe òwọn gogó ńǹkan ti wọn lo faá.

L'àpèjúwé, o sọ wipe ilé ìwòsàn náà ma ń lo mímlíọ́nù maárun din ní igba egbèrun (4.8M) lori epó jẹ́nẹ́rétọ̀ l'oṣooṣù.

O tún s'àlàye wipe owó ogun àtí ńǹkan ìṣegun òyinbo ti wọn si.

O sọ wipe gbogbo ẹni to ba ni ìwe tí ìjọba ìpinlẹ̀ náà fí p'àṣẹ́ sisọ owó ìgbẹ̀bi alábóyún dí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹdọ́gbọ̀n (N25,000) ko mú ìwé náà jadé.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: