Ọlọ́pàá Kwara: À ń wá àwọn adigunjalè tó pa èèyàn méjìlá

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÒkú sùn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè ní Ọ̀ffà

Ile-isẹ ọlọpa lorilẹede Naijiria sọ wipe awọn n wa awọn adigunjale to yin ibọn pa ọlọpa mẹfa ati awọn ara ilu mẹfa nigba ti wọn ṣe ikọlu si ile ifowopamọ marun ni ilu Ọffa ni ipinlẹ Kwara to wa ni ẹkun iwọ oorun orilẹede Naijiria.

Awọn tọ rọ naa soju rẹ sọwipe awọn adigunjale naa ya bo agọ ọlọpa to wa ni agbegbe naa, ti wọn si pa awọn ọlọpa ati awọn to wa fẹjọ sun ni agọ ọlọpa, ko to di wipe wọn wa bẹrẹ si ni lọ si awọn ile ifowopamọsi lati lọ ja wọn ni ole.

Image copyright Ayobami Agboola
Àkọlé àwòrán Ńse ni òkú èèyàn kún ilẹ̀ káàkiri ìlú Ọ̀ffà nítorí Ìsẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè náà

Agbẹnusọ fun ile isẹ ọlọpa ni ipinlẹ naa, Ajayi Okasanmi so fun BBC Yoruba wipe awọn ọlọpa n se iwadii atiwipe awọn n sisẹ papọ pẹlu awọn adari awọn ile ifowopamọsi ti wọn se ikọlu si lati le tọ pasẹ awọn adigunjale naa.

Arakunrin Okasanmi sọwipe awọn ti ri lara awọn ọkọ ayọkẹlẹ ti awọn adigunjale naa lo, ti o si sọwipe awọn ọlọpa lo fara kaasa isẹlẹ naa ju nigba ti awọn adigunjale naa da ibọn bo ile.

Image copyright Ayobami Agboola
Àkọlé àwòrán Ńse ni òkú èèyàn kún ilẹ̀ káàkiri ìlú Ọ̀ffà nítorí Ìsẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè náà

Ile ifowopamọsi igbalode marun ni wọn se ikọlu naa si, ti wọn si lo ado oloro lati fi fọ ibi ifowopamọsi naa, eleyi ti awọn ti ọrọ naa soju rẹ sọwipe o ti di lemọlemọ.

Amọ awọn adari ile ifowopamọsi naa ko ba BBC ni gbolohun pọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: