Ọmọ ilẹ̀ Kenya gbé ‘búrọ́ọ̀ṣì ìfọyín’ mì nígbà tó ǹ fọyín

Aworan burọsi ifọyin Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Bawo ni burọsi ifọyin se le de ikun eniyan?

Bo ti lẹ jẹ wipe o ya eniyan lẹnu julọ, awọn dokita lorilẹede Kenya ti yọ burọọsi ifọyin kuro ni ikun arakunrin kan to gbe e mi.

Arakunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ, David Charo sọ wipe oun ṣeeṣi gbe burọọsi ifọyin naa mi nigba t'oun fọ ẹyin rẹ.

Arakunrin naa ti lọ si ile iwosan bii marun ki o to di wipe o ri ile iwosan ti yoo ran lọwọ lati yọ ohun elo ifoyin naa kuro ninu rẹ, lẹyin ti iwadi fihan wipe lootọ ni burọọsi naa wa ninu rẹ.

Ati wipe ile iṣẹ iroyin lorilẹede naa pin aworan burọọsi naa lẹyin ti awọn dokita ṣe iṣẹ abẹ to yọ ohun ifọyin naa kuro ninu rẹ.

Awọn eniyan lori ikanni ibaraẹnisọrọ lori opo Twitter fi ero wọn han lori iṣẹlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Related Topics