Kókó ìròyìn t'òní: Ìjọba Òǹdó lórí owó aboyún, Ìdigunjalé l’Ọ́ffà

Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.

Ilé ìwòsàn Àkúrẹ́ ṣ'àlàyé lorí ìfowó kun owó ìbimọ

Oríṣun àwòrán, APROKO GIRL

Olùdarí ilé ìwòsàn ìjọbá Àkúrẹ́, dókítà Moses Adewọle, tí sàlàyé pe òwọn gógó ńǹkan lo faá ti wọn fi fi owó kun owó ìgb'ẹ̀bi.

Olùdarí ilé ìwòsàn náà sọ wipe ìwọdẹ́ ti àwọn aláboyún ṣe ni Ọjọ́bọ̀ (Thursday) ní àpẹrẹ òṣelù nínú.

Ọlọ́pàá Kwara ń wá àwọn adigunjalè tó pa èèyàn méjìlá

Oríṣun àwòrán, Ayobami Agboola

Àkọlé àwòrán,

Ńse ni òkú èèyàn kún ilẹ̀ káàkiri ìlú Ọ̀ffà nítorí Ìsẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè náà

Ile-isẹ ọlọpa lorilẹede Naijiria sọ wipe awọn n wa awọn adigunjale to yin ibọn pa ọlọpa mẹfa ati awọn ara ilu mẹfa nigba ti wọn ṣe ikọlu si ile ifowopamọ marun ni ilu Ọffa ni ipinlẹ Kwara to wa ni ẹkun iwọ oorun orilẹede Naijiria.

Awọn tọ rọ naa soju rẹ sọwipe awọn adigunjale naa ya bo agọ ọlọpa to wa ni agbegbe naa, ti wọn si pa awọn ọlọpa ati awọn to wa fẹjọ sun ni agọ ọlọpa, ko to di wipe wọn wa bẹrẹ si ni lọ si awọn ile ifowopamọsi lati lọ ja wọn ni ole. Ẹ ka ẹkunrẹrẹ rẹ ni bii

Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni

Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC

Fidio wa fun toni

Òkú sùn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè ní Ọ̀ffà

Àkọlé fídíò,

Òkú sùn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè ní Ọ̀ffà